ASA IGBEYAWO NI ILEE YORUBA
Igbeyawo je isopo laaarin okunrin ati obinrin ti o ti balaga, lati jo maa gbe po gege bi oko ati aya.
IGBESE ATI ILANA IGBEYAWO ABINIBI ILE YORUBA
I. IFOJUSODE : Ifojusode maa n waye nigba tie bi kan ba n wa iyawo fun omo won okunrin ti o ti balaga.
2. IWADII : Awon ebi omokunrin yoo bere sii se iwadii nipa idile ti won ti fe fe obinrin , nitori pe orisirisi idile lo wa idile miiran arun buburu a maa yo won lenu bi apeere; arun aganna, warapa, abisinwin abbl. Idile miiran awon obinrin won kii gbe ile oko dale, idile miiran igbese jije a maa ro won lorun, idile miiran won kii dagba, won yoo tun te siwaju lati se iwadii iru eniyan ti omobinrin naa je boya asa omo ni, boya oni kebekebe ni, leyin eyi ni won yoo wa lo beere lowo ifa gege bi Eleri-ipin ti ko lee puro , gbogbo asiri ojo ola igbeyawo naa ni yoo han kedere lati odo ifa.
3. ALARINA : Alarina je okunrin tabi obinrin ti o sun mo omobinrin , o le je ore tabi molebi obinrin oun ni eni ti o n ye ona fun omokunrin ti o fe fe iyawo ki awon mejeeji to pade.
4. ISIHUN: Isihun ni gbigbo ati gbigba ti omobirin gba lati je ki omokunrin naa je afesona oun. Omokunrin yii yoo wa son owo isihun fun awon ebi omobinrin yii ki o to le maa ba omobinrin naa soro, owo naa je oke kan laye atijowon yoo si fi obi abata, ataare, ati orogbo si owo isihun naa.
5. ITORO : Awon obi ati die ninu ebi omokunrin yoo lo si ile obi omobinrin lati so fun won pea won nife si omo won obinrin lati fe. Awon obi omobinrin yii yoo dajo fun awon ebi omokunrin pe ki won pada wa , o le je leyin ojo meje tabi ju bee lo, awon ebi omobinrin yii naa yoo lo se iwadii nipa iru idile ti omokunrin naa ti jade, iru eniyan ti oun funra re je, won yoo te siwaju lati se iwadii lowo ifa bi ojo iwaju igbeyawo naa yoo se ri, ti iwadii won ba yori sir ere, gbigbo ati gbigba ti awon obi omobinrin gba lati fi omo won obinrin yii gege bi aya ni awon Yoruba n pe ni IJOHEN tabi baba gbo iya gbo.
6. IDANA : Idana je fife obinrin nisu loka, kiko awon eru idana lo si ile obi obinrin gege bi asa Yoruba, awon nnkan idana bii: isu,obi, orogbo,aadun, ataare,ireke, iyo, epo, oyin,eja-osan, ati owo-ori iyawo.
7. AYEYE-IGBEYAWO: Ojo ayeye igbeyawo je ojo iyi ati eye fun iyawo,oko-iyawo ati awon ebi won. Ni irole ojo ti iyawo yoo re ile oko re , leyin ti o ba ti mura tan, yoo lo dagbere fun awon obi re ati awon ebi, akoko yii ni iyawo yoo maa sun ekun iyawo lati fi dagbere , lati fi dupe ati lati fi gba ire/adura lenu awon obi ati ebi re, awon ore re yoo si maa tele e bi o ti n sun ekun –iyawo kiri won yoo maa re e lekun. Asale ni yoo to dari pada si odo awon obi re, leyin iwure baba yoo fa iyawo le owo obinrin ti o je agba ninu awon ebi oko lowo, awon iyawo- ile ati awon ore iyawo yoo fi ilu ati orin tele e lo si ile oko re.Oko iyawo ti gbodo kuro ni ile ki won to mu iyawo re de, eewo ni ni ile Yoruba iyawo ko gbodo ba oko re nile ni ale ojo igbeyawo won, leyin ti won ba ti mu iyawo wole tan ni oko iyawo yoo to wole wa. Awon iyaale iyawo yoo bu omi tutu si ese iyawo tuntun lenu ona abawole, igbagbo awon Yoruba nipa eyi ni wipe ki iyawo le fie se ero wole oko re. Leyin eyi won yoo doju igba gbigbe dele ki iyawo tuntun fie se fo o, awon Yoruba ni igbagbo pe iye ona ti igba yii fo si ni iye omo ti iyawo yoo bi, ti o ba wuu o le ma bi to bee tabi ki o bi ju bee lo.
IBALE: Oko-iyawo ati iyawo re yoo jo ni ibalopo fun igba akoko ni ale ojo igbeyawo won lati mo boya iyawo tuntun yii ko I tii mo okunrin ri. Awon obi oko yoo tite aso funfun si ori ibusun ninu yara oko iyawo lati fi gba ibale iyawo re. Iyi nla ni fun awon obi iyawo ti oko re ba nile, o tumo si wipe omobinrin naa ko tii mo okunrin ri. Odidi agbe emu tabi odidi paali isana,iyan ati obe ti o dara ni awon ebi oko-iyawo yoo gbe lo fun awon obi iyawo laaro kutu ojo keji lati fi dupe lowo won wipe odidi ni won ba omo won , eyi ni ounje ibale, iyawo yoo tun gba owo ibale tii se oke-meji lowo oko re. Itiju ati abuku ni fun iyawo ti oko re ko b anile, ilaji agbe emu tabi ilaji paali isana ni awon obi oko iyawo yoo fi ranse si awon obi iyawo ti oko re ko b anile lati le je ki won mo wipe omo won ti mo okunrin ri.
IKORUN: Ojo karun un ti iyawo wole oko re ni yoo to jade sita, lati se ise-ile akoko ati lati lo ki awon ebi oko re. Ojo yii naa ni yoo je igba akoko ti yoo dana ounje fun oko re. #omooduduwa
Source of Article: https://www.orisa.com.ng
AJE NLA the son of OBATALA is registered with CAC No: 8022733
This Article was written by AJE NLA the son of OBATALA with +2347031178647.
You can contact AJE NLA for ...
ODU OBATALA Consultation
Egbe Orun INITIATION
OSUN Initiation
Begging of the elders
Feeding of ORISA OSUN, OBATALA, Egbe Orun, TAJENIKARO (AJE that fights for your wealth), AJELETI (AJE from IYAAMI), ONIMERE (for all Emere), AJASORO (Revenge and door opener), AJE OLOKUN, ESU, ELEGBA (Justice and way opener) etc.
Discover more from ORISA BLOG
Subscribe to get the latest posts sent to your email.