IBADAN
Ibadan mesi Ogo,
nile Oluyole.
Ilu Ogunmola,
olodogbo keri loju ogun.
Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya.
Ilu Ajayi,
o gbori Efon se filafila.
Ilu Latosa,
Aare-ona kakanfo.
Ibadan Omo ajoro sun.
Omo a je Igbin yoo,
fi ikarahun fo ri mu.
Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni,
eyi too ja aladuugbo gbogbo logun,
Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun.
Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o,
Ni bi Olè gbe n jare Olohun.
B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji.
Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu.
Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan.
A ki waye
ka maa larun kan lara,
Ija igboro larun Ibadan.
Discover more from ORISA BLOG
Subscribe to get the latest posts sent to your email.