L’óde òní, ayé ti d’ayé òyìnbó; Òpòlopò
àwon ìdíwó tí ènìyàn ń ní ní ayé àtijó ti rora ńkásè ní’lè díèdíè. Ìdí èyí síì ni wípé ilé ìwòsán wà káàkiri Ilè wa.
Kí á tó rìn ogójì ìbùsò sí ibikíbi ní Ilè káàrò, ò jíire yìí, a ní láti kan Ilé ìwòsán kan. Òpòlopò àrà ni àwon onísègùn sí lè dà pèlú egbòogi won.
Nítorí Ìdí èyí, ó dàbí eni wípé a ti ńgbàgbé díèdíè bí a ti ńse ìtójú àwon omodé wa kí àwon onísègùn òyìnbó wònyí tó dé Ilè wa.
Ní ayé àtijó, omodé sòro láti tójú lópòlopò. Òpòlopò àwon oògùn òyìnbó tí ó wà l’óde òní, kò sí ní ayé àtijó rárá.
Àwon oògùn tí nwón ńlò ní ayé àtijó náà ni àgbo. Orísirísi àgbo ni ó sì wà.
Àgbo Wóbó : Nígbà tí ikùn omo bá bèrè sí se wóbówóbó, tí ó sì ń pa’riwo súnrúnrúnrún, nwón yóò mò wípé àgbo wóbó ni nwón yóò tó fún omo.
Tí nwón bá sì tì tó èyí lóotó, omodé yóò yàgbé wórówóró, ara rè yóò sì dá.
Àgbo Jèdíjèdí: Nígbà tí omodé bá fé yàgbé, dípò kí ó rora yàgbé, tí Ìdí rè bá bèrè sí pariwo pèrèpèrè, tí ìgbé kò sì wá, nwón yóò ti mò wípé jèdí ńyo omo lénu nìyen.
Tí nwón bá sì ti tó àgbo rè fún omo, ara rè yóò tún yá gágá.
Àgbo Joríjorí: Tí a bá wòó orí omo mìíràn, ní se ni yóò là sí méjì gbàràgàdà, tí gbogbo isan tí ó wà níbè yóò sì Hàn pérépéré. Nígbà mìíràn, àwùjè omo náà yóò la enu sílè kekeje, yóò sì máa mí gulegule. Bí irú èyí bá selè, a máa ńrò pé joríjorí mbá omo jà. Tí nwón bá sì tó àgbo fún omo ara omo yóò bère sí dá díèdíè.
Àgbo Gìrì: Gìrì yìí jé okàn ní’nú u àwon àìsàn tí ó ń lu omo pa láì rò tèlè. Látí kékeré ni nwon yóò ti bèrè sí fún omo ní Àgbo yìí, dípò kí ara omo síì le kankankan ń sé ni ara rè yóò rò gbèjègbèjè. Kò sí bí àìlera náà ti le pò tó, gìrì Kò ní wò ó.
Àgbo Ehín : Láti ìgbà tí omo bá ti pé omo osù méjì tàbí méta ni won yóò ti bèrè sí fún un ní àgbo ehín. Bí wón ti ńse Àgbo yìí, béè náà ni nwon yíò máa se ose rè. Tí nwón bá lo èyí dáradára, omo Kò ní ní wàhálà kankan nípa pé à ń hu ehín.
Àwon Yorùbá gbàgbó wípé ehín ìsàlè ni ó dára kí omó kókó mú jáde. Tí nwón bá ti rí wípé omó fé tètè mú eyín òkè jáde sáájú ti ìsàlè, orísirísi òògùn ni nwon yóò kó tí í kí ó le pa eleyi sori. Ìdí rè ni wípé nwón gbàgbó pé bí omo bá lo fi ehín èléèyí jáde sáájú, omo náà yóò sàmúdí lópòlopò nípa mímú ehìn náà síta.
Sùgbón tí omó bá bèrè nípa fífi ehín ìsàlè jáde, àlàáfíà gbáà ni.
Ó férè jé gbogbo àìsàn tí ó ńse omodé ni à ńtó àgbo fún, à ńtó fún ibà, à ńtó fún ikó, à ńto fún inú kíkún, à ntó fún ìgbé gbuuru.
Nígbà tí omó bá ti ńtó omo odún márùn ún tàbí méfà, omo tí ńgbónrà nìyen, kò sí wípé à ń ró o l’ágbo lójoojúmó mó. Okùnrin tàbí Obìnrin sí ti dé nìyen…
Source of Article: https://www.orisa.com.ng
This Article was written by AJE NLA the son of OBATALA +2347031178647.
You can contact AJE NLA for ...
ODU OBATALA Consultation
Egbe Orun INITIATION
OSUN Initiation
Begging of the elders
Feeding of ORISA OSUN, OBATALA, Egbe Orun, TAJENIKARO (AJE that fights for your wealth), AJELETI (AJE from IYAAMI), ONIMERE (for all Emere), AJASORO (Revenge and door opener), AJE OLOKUN, ESU, ELEGBA (Justice and way opener) etc.
Related Post
Discover more from ORISA BLOG
Subscribe to get the latest posts sent to your email.