Sunday, June 11, 2023

Different herbs for taking care of Children

SHARE
L’óde òní, ayé ti d’ayé òyìnbó; Òpòlopò 

àwon ìdíwó tí ènìyàn ń ní ní ayé àtijó ti rora ńkásè ní’lè díèdíè. Ìdí èyí síì ni wípé ilé ìwòsán wà káàkiri Ilè wa. Kí á tó rìn ogójì ìbùsò sí ibikíbi ní Ilè káàrò, ò jíire yìí, a ní láti kan Ilé ìwòsán kan. Òpòlopò àrà ni àwon onísègùn sí lè dà pèlú egbòogi won.Nítorí Ìdí èyí, ó dàbí eni wípé a ti ńgbàgbé díèdíè bí a ti ńse ìtójú àwon omodé wa kí àwon onísègùn òyìnbó wònyí tó dé Ilè wa.Ní ayé àtijó, omodé sòro láti tójú lópòlopò. Òpòlopò àwon oògùn òyìnbó tí ó wà l’óde òní, kò sí ní ayé àtijó rárá. Àwon oògùn tí nwón ńlò ní ayé àtijó náà ni àgbo. Orísirísi àgbo ni ó sì wà.Àgbo Wóbó : Nígbà tí ikùn omo bá bèrè sí se wóbówóbó, tí ó sì ń pa’riwo súnrúnrúnrún, nwón yóò mò wípé àgbo wóbó ni nwón yóò tó fún omo. 


Tí nwón bá sì tì tó èyí lóotó, omodé yóò yàgbé wórówóró, ara rè yóò sì dá.


Àgbo Jèdíjèdí: Nígbà tí omodé bá fé yàgbé, dípò kí ó rora yàgbé, tí Ìdí rè bá bèrè sí pariwo pèrèpèrè, tí ìgbé kò sì wá, nwón yóò ti mò wípé jèdí ńyo omo lénu nìyen. Tí nwón bá sì ti tó àgbo rè fún omo, ara rè yóò tún yá gágá.


Àgbo Joríjorí: Tí a bá wòó orí omo mìíràn, ní se ni yóò là sí méjì gbàràgàdà, tí gbogbo isan tí ó wà níbè yóò sì Hàn pérépéré. Nígbà mìíràn, àwùjè omo náà yóò la enu sílè kekeje, yóò sì máa mí gulegule. Bí irú èyí bá selè, a máa ńrò pé joríjorí mbá omo jà. Tí nwón bá sì tó àgbo fún omo ara omo yóò bère sí dá díèdíè.
Àgbo Gìrì: Gìrì yìí jé okàn ní’nú u àwon àìsàn tí ó ń lu omo pa láì rò tèlè. Látí kékeré ni nwon yóò ti bèrè sí fún omo ní Àgbo yìí, dípò kí ara omo síì le kankankan ń sé ni ara rè yóò rò gbèjègbèjè. Kò sí bí àìlera náà ti le pò tó, gìrì Kò ní wò ó.
Àgbo Ehín : Láti ìgbà tí omo bá ti pé omo osù méjì tàbí méta ni won yóò ti bèrè sí fún un ní àgbo ehín. Bí wón ti ńse Àgbo yìí, béè náà ni nwon yíò máa se ose rè. Tí nwón bá lo èyí dáradára, omo Kò ní ní wàhálà kankan nípa pé à ń hu ehín. Àwon Yorùbá gbàgbó wípé ehín ìsàlè ni ó dára kí omó kókó mú jáde. Tí nwón bá ti rí wípé omó fé tètè mú eyín òkè jáde sáájú ti ìsàlè, orísirísi òògùn ni nwon yóò kó tí í kí ó le pa eleyi sori. Ìdí rè ni wípé nwón gbàgbó pé bí omo bá lo fi ehín èléèyí jáde sáájú, omo náà yóò sàmúdí lópòlopò nípa mímú ehìn náà síta.
 Sùgbón tí omó bá bèrè nípa fífi ehín ìsàlè jáde, àlàáfíà gbáà ni.
Ó férè jé gbogbo àìsàn tí ó ńse omodé ni à ńtó àgbo fún, à ńtó fún ibà, à ńtó fún ikó, à ńto fún inú kíkún, à ntó fún ìgbé gbuuru. Nígbà tí omó bá ti ńtó omo odún márùn ún tàbí méfà, omo tí ńgbónrà nìyen, kò sí wípé à ń ró o l’ágbo lójoojúmó mó. Okùnrin tàbí Obìnrin sí ti dé nìyen…

This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647).For the following:::

IFA consultation and Divination

Egbe Orun initiation

Appeasement of Egbe Orun

Yes and No questions

Feeding of Ori (inner head)

Feeding of ORISA

IFA INITIATION

Solutions to Problems

Source: https://www.orisa.com.ng

SHARE

Author: verified_user

AJE NLA Spiritual Traveller | OLOBATALA | OMO OLOKUN, OMO ORISA | BABALAWO OMO ORUNMILA | CEO www.orisa.com.ng | +2347031178647 For IFA Consultation, Divination, Yes / No questions , spiritual guidance, Dream interpretation etc whatsapp https://wa.me/2347031178647

0 $type={blogger}: