Ọ̀ṢUN CONSECRATION 
ORÍKÌ Ọ̀ṢUN
Ọ̀ṣun is the Yoruba Orisa of love, intimacy, beauty, fertility, and wealth. She is compassionate and sensuous in nature, and she uses her water-element energy for healing and nurturing. 
She is the Òrìṣà who presides over the divinity of the Ọ̀ṣun river.
Ọ̀ṣun ṣéǹgẹ̀ṣẹ́ olóòyà iyùn!
Arẹwà obìnrin, alágbo l’ódò
A’wẹ’dẹ’wẹ’mò, af’idẹ-rẹ’mọ
Apẹ́níbú-ṣọlá, apẹ́lódò-ṣ’ọrọ̀ ọmọ
Ọ̀ṣun abú’ra Olú
Òwa’yanrìn’wa’yanrìn ko’wósí!
Ọ̀ṣun oníkìí, ẹni idẹ kìí sún
Òyéye-n’ímọ̀, amọ-awo-má-rò
Omi-amọ̀ọ́-rìn, omi a-mọ̀ọ́ sun
Obìnrin gb’ọ̀nà, ọkùnrin ń sá
Ọ̀gbàdàgbàdà l’ọ́yàn
Gbàdàmùgbádámú obìnrin kò ṣe é gbámú!
Oore Yèyé Ọ̀ṣun!
Látójokú, Yèyé ọ̀pọ̀
Ìyá ab’óbìrin gb’àtọ̀, Ládékojú ab’ọ́kùnrin gb’ase
Ìyá tí kò l’éegun tí kò l’ẹ́jẹ̀
Ladekoju ebora tí ń gbé nù omi
Elétíi gb’áròyé, ọ̀gbàgbà tí ń gb’ọmọ rẹ̀ l’ọ́jọ́ ìjà!
Yèyé mi ọl’ọ́wọ́ aró
Yèyé mi ẹlẹ́sẹ̀ osùn
Yèyé mi a’jímọ́-roro
Yèyé mi a’bímọ má yànkú
Yèyé mi aláàgbo àwẹ̀yè
Aríbáni-gbọ́-nípa-t’ọmọ!
Oore Yèyé gbà mí, ẹni a ní ní ń gba ni!
Omi oooo!
Ọta oooo!
Ẹri oooo!
Ẹdan oooo!
Ẹ k’óre Yèyé Ọ̀ṣun oooooo!
Ọ̀ṣun mà ń bọ̀ o – Yàgò lọ́nà o
Oore Yèyé mà ń bọ̀ o – Yàgò lọ́nà o

Source of Article: https://www.orisa.com.ng

AJE NLA the son of OBATALA is registered with CAC No: 8022733

This Article was written by AJE NLA the son of OBATALA with +2347031178647.

You can contact AJE NLA for ...

ODU OBATALA Consultation

Egbe Orun INITIATION

OSUN Initiation

Begging of the elders

Feeding of ORISA OSUN, OBATALA, Egbe Orun, TAJENIKARO (AJE that fights for your wealth), AJELETI (AJE from IYAAMI), ONIMERE (for all Emere), AJASORO (Revenge and door opener), AJE OLOKUN, ESU, ELEGBA (Justice and way opener) etc.


Discover more from ORISA BLOG

Subscribe to get the latest posts sent to your email.

By AJE NLA

Leave a Reply

Translate »