Sunday, June 11, 2023

Oriki ORISA OSUN / Ọ̀ṢUN CONSECRATION (oriki OSUN / Oshun / Oshun)

SHARE
Ọ̀ṢUN CONSECRATION 

ORÍKÌ Ọ̀ṢUN


Ọ̀ṣun is the Yoruba Orisa of love, intimacy, beauty, fertility, and wealth. She is compassionate and sensuous in nature, and she uses her water-element energy for healing and nurturing. 


She is the Òrìṣà who presides over the divinity of the Ọ̀ṣun river.Ọ̀ṣun ṣéǹgẹ̀ṣẹ́ olóòyà iyùn!

Arẹwà obìnrin, alágbo l'ódò

A'wẹ'dẹ'wẹ'mò, af'idẹ-rẹ'mọ

Apẹ́níbú-ṣọlá, apẹ́lódò-ṣ'ọrọ̀ ọmọ
Ọ̀ṣun abú'ra Olú

Òwa'yanrìn'wa'yanrìn ko'wósí!

Ọ̀ṣun oníkìí, ẹni idẹ kìí sún

Òyéye-n'ímọ̀, amọ-awo-má-rò

Omi-amọ̀ọ́-rìn, omi a-mọ̀ọ́ sun

Obìnrin gb'ọ̀nà, ọkùnrin ń sá

Ọ̀gbàdàgbàdà l'ọ́yàn


Gbàdàmùgbádámú obìnrin kò ṣe é gbámú!


Oore Yèyé Ọ̀ṣun!

Látójokú, Yèyé ọ̀pọ̀

Ìyá ab'óbìrin gb'àtọ̀, Ládékojú ab'ọ́kùnrin gb'ase

Ìyá tí kò l'éegun tí kò l'ẹ́jẹ̀

Ladekoju ebora tí ń gbé nù omi

Elétíi gb'áròyé, ọ̀gbàgbà tí ń gb'ọmọ rẹ̀ l'ọ́jọ́ ìjà!Yèyé mi ọl'ọ́wọ́ aró

Yèyé mi ẹlẹ́sẹ̀ osùn

Yèyé mi a'jímọ́-roro

Yèyé mi a'bímọ má yànkú

Yèyé mi aláàgbo àwẹ̀yè

Aríbáni-gbọ́-nípa-t'ọmọ!

Oore Yèyé gbà mí, ẹni a ní ní ń gba ni!Omi oooo!
Ọta oooo!

Ẹri oooo!

Ẹdan oooo!

Ẹ k'óre Yèyé Ọ̀ṣun oooooo!


Ọ̀ṣun mà ń bọ̀ o - Yàgò lọ́nà o


Oore Yèyé mà ń bọ̀ o - Yàgò lọ́nà oThis Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647).For the following:::

IFA consultation and Divination

Egbe Orun initiation

Appeasement of Egbe Orun

Yes and No questions

Feeding of Ori (inner head)

Feeding of ORISA

IFA INITIATION

Solutions to Problems

Source: https://www.orisa.com.ng

SHARE

Author: verified_user

AJE NLA Spiritual Traveller | OLOBATALA | OMO OLOKUN, OMO ORISA | BABALAWO OMO ORUNMILA | CEO www.orisa.com.ng | +2347031178647 For IFA Consultation, Divination, Yes / No questions , spiritual guidance, Dream interpretation etc whatsapp https://wa.me/2347031178647

0 $type={blogger}: