Sunday, June 25, 2023

ORO ATI GBOLOHUN ONIPON-NA

SHARE
ORO ATI GBOLOHUN ONIPON-NA


Pon-na ni ki oro, apola tabi gbolohun kan ni ju itumo kan lo. Pon-na yato si oro apola tabi gbolohun ti ko ni itumo kan pato, lara oro-oruko tabi oro-ise ni a ti maa n ri oro onipon-na ninu ede Yoruba. 
Bi apeere:

Oro-oruko : OYIN – 

1. Oruko eniyan 

2. Orisii kokoro kan 

3. Ohun alaadun ti a n ri lati ara kokoro tabi igi kan.(ireke)


Oro-ise : GBE -

1. Ki a ko nnkan nile 

2. Ki eniyan ja ole 

3. Ki eniyan wa ninu isoro 

4. Ibi ti a fi se ibujokoo.


AWON ONA TI ORO ONIPON-NA GBA WAYE


1. Ilo oro eyo kan laarin gbolohunle so gbolohun bee di onipon-na. 

bi apeere : 

Ayo lo pa a : eyi le tumo si

(1) idunu ni o fi fa iku si ori ara re 
(2) Ayo ni eni ti o fi nnkan lu u ti o fi ku


2.     Ailo amin ohun si ori oro. 

Bi apeere : IGBA : 

a le ri awon itumo wonyi : 

(i) Ogorun-un meji (ii) Asiko (iii) Orisii eso ara igi kan (iv) ohun ti awon obinrin maa lo lati fir u eru


3.     Ti oro ko ba si ni kiko sile, bi o ti dun leti ni a o fi se itumo re. 


Bi apeere Bamiji Ojo (i) Pipe oruko eniyan (ii) Bamiji o jo (iii) Ba mi ji Ojo.


4.     Pon-na maa waye ni igba ti oro ba ni ohun kan naa yala ni kiko sile tabi ni pipe lenu. 


Bi apeere : RA : (i) ki nnkan baje (ii) Ki eniyan sanwo oja


5.     Lilo oro bi akanlo ede. 

Bi apeere : Baba Ade lawo :
(i) Baba Ade ko lahun (akanlo ede) (ii) Baba Ade ya owo re ti a si ri (itumo adamo)


6.     Ti isunki tabi aranmo ba waye ninu apola oro. 


Bi apeere : Kaso : le tumo si ‘ko aso’ tabi ‘ka aso’ . Foko :
le tumo si ‘fo eko’ tabi fe oko’7. Lilo oro asopo bi ati, ayafi tabi afi. 

Bi apeere :

Folasade feran iresi ati ewa. (a) Folasade feran iresi, o tun feran ewa. (b) Folasade feran lati maa je mejeeji po.

This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647).For the following:::

IFA consultation and Divination

Egbe Orun initiation

Appeasement of Egbe Orun

Yes and No questions

Feeding of Ori (inner head)

Feeding of ORISA

IFA INITIATION

Solutions to Problems

Source: https://www.orisa.com.ng

SHARE

Author: verified_user

AJE NLA Spiritual Traveller | OLOBATALA | OMO OLOKUN, OMO ORISA | BABALAWO OMO ORUNMILA | CEO www.orisa.com.ng | +2347031178647 For IFA Consultation, Divination, Yes / No questions , spiritual guidance, Dream interpretation etc whatsapp https://wa.me/2347031178647

0 $type={blogger}: