EULOGY OF SÀNGÓ
Sàngó oníbọn ọ̀run
Olúbámbí arígba ota ségun
Afìrì wọ̀wọ̀ òjò sẹ́tẹ̀ ọlọ̀tẹ̀
Ààrá wàá
Ààrá wòó
Ààrá wàwàǹwówó
Sángiri
Làgiri
Ọ̀làgiri kàkàkà figba ẹdun bọ̀
Akọ ológbò tí wẹ̀wù òdòdó
Ají fẹ̀jẹ̀ àgbò bójú
Aránmọlógun bọ́mọ lọ
Ajágbe másebi kótó pasebi
Olóògùn ìkìyà
Olóògùn ìlàyà
Onígbètugbètu
Éégún tó ń yọná lénu
Sàngó olówó ẹyọ
Ẹkùn ọkọ Ọya
Ààrá bọwọ́ ìjà lálá
Iná gorí ilé fẹjú
Ikú tíí pani t'ẹni kan kìí ké
Afosé yọni lójú
Afẹdùn yọ̀fun
Afèéfín seni ní pẹlẹ
Afiná fọhùn bí o sọrọ.
Translation
Sángó, the owner of the gun in Heaven
Olúbámbi, who possesses two hundred stones with which he conquers enemies
He who uses minor rain to destroy the rebels
The thunder that sounds "wáá!"
The thunder that sounds "wóó!"
The thunder that sounds "wáwáhwówó!"
He who cracks wall
He who splits wall
He who splits wall and sends in two hundred stones
The male cat that wears red cloth
He who uses ram's blood to wash his face early in the morning
He who sends one to the war without leaving the person alone
He who shouts at the bad person before killing him
The owner of the charm that makes one extraordinarily courageous
The owner of the charm that imposes fear on people
The owner of the charm that is used to control people
The masquerader that spits fire
Sángó, the owner of cowries
Leopard, the husband of Oya
The thunder with long hands of fight
The fire that spread on the roof
The death that kills one where nobody dares to weep
He who uses his axe to remove eyes
He who uses his stone to remove intestine
He who speaks with fire.
Reference: FÁYẸMÍ FÁTÚNDÉ FÁKÁYỌ̀DÉ, IWÚRE, Efficacious Prayer to Olódùmarè, The Supreme Force.
This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647) For spiritual guidance...We also sell spiritual product for wealth, protection and Open doors.
Post a Comment