no fucking license
Bookmark

Ogbè Wẹ̀yìn (Ogbè Ìwòrì)

Ogbè Wẹ̀yìn (Ogbè Ìwòrì)


Ọ̀rúnmìlà wi ègbé ni
Mo ní ègbé ni Baraà mi Àgbọnnìrègún
Ó ní orin táa kọ l’étí Adití ńkọ́?
Wọ́n ní orin náà dùn l’ádùn jù
Ọ̀rúnmìlà ni ègbé ni
Nítorí kò gbọ́



Ọ̀rúnmìlà wi ègbé ni
Mo ní ègbé ni Baraà mi Àgbọnnìrègún
Ó ní ijó táa jó l’ójú Afọ́jú ńkọ́?
Wọ́n ní ijó náà dùn l’ádùn jù
Ọ̀rúnmìlà ni ègbé ni
Nítorí kò ri i



Ọ̀rúnmìlà wi ègbé ni
Mo ní ègbé ni Baraà mi Àgbọnnìrègún
Ó ní eré táa bá aya al’áya ṣe ńkọ́?
Wọ́n ní eré náà dùn l’ádùn jù
Ọ̀rúnmìlà ni ègbé ni
Nítorí ikú ló wà ní’bẹ̀
Ọmọ t’ó bá ti ibẹ̀ jáde kìí ṣe t’ẹni

This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647) For spiritual guidance...We also sell spiritual product for wealth, protection and Open doors.

Post a Comment

Post a Comment