Awó r'Áwo lóòní
Awo Àlúkúìjí
Àgbìgbò ṣe rànhìn rànhìn máfò
Awo Ọ̀wáràngún Àbọṣíṣẹ
Dífá fún Ọ̀wáràngún Àbọṣíṣẹ
Níjọ́ tí eerin mẹ́rìndínlógún kú sí òkè Ìjerò
Wọ́n ní kí Alárá ó kun mẹ́rin
Wọ́n ní kí Ajèrò ó kun mẹ́rin
Kí ọba lẹ́yọ̀ ó kun mẹ́rin
Kí Ọ̀ọ̀ni Àlàká Èṣùú ó kun mẹ́rin
Kí wọ́n ó lọ rèé kó ìjàǹjá inú ẹ̀ fún Ọ̀ràngún
Ọ̀ràngún ní òun kìí jẹ ìfun ẹran kẹ́ran
Wọ́n ní Ọ̀ràngún s'àfojúdi
Wọ́n ní Ọ̀ràngún s'àgbọdọ̀ràn
Wọ́n wá ní kí Alárá ó gbógun
Kó lọ sí Mọ̀pó ilé
Kí Ajèrò ó gbógun
Kó lọ sí Mọ̀nà àkunfà
Kí ọba lẹ́yọ̀ ó gbógun
Kó lọ sí oríta mẹ́ta Ìṣhẹri mele
Kí Ọ̀ọ̀ni Àlàká Èṣùú ó gbógun
Kí ó lọ sí oríta mẹ́ta ayé òun ọ̀run
Ọ̀ràngún ní ééṣò!
Tí òun ò jáwé ata láta
Tí òun ò wegbò ata láta
Ó ní ẹnìkan kìí ṣígún ṣígún kó mú aáyán
Ẹnìkan kìí dìtẹ̀ dìtẹ̀ kómú èèrà
Àmìnù ni kùkùté ó mira rẹ̀ ṣ'ólóko
Ayé lọ̀tá mi yóò fimí sí
Ayé lọ̀tá mi yóò padà wá bá mi
Nítorí wípé àbọ̀ wá bá ni ti pèrègún igbódù
Ogun gbọ́dọ̀ ṣá!
Ogun gbọ́dọ̀ họ!
Kọ̀ǹkọ̀ ń dún họ họ̀ họ!
Awo ni ó ṣẹ́gun ọ̀tá ilé
Awo ni ó rẹ́yìn odì òde
Awo ni yíò ma jẹjà
Ọ̀jà ò ní jẹ Awo láí láí
Àgbàlé ọ̀ṣẹ̀ o!
- Ọ̀yẹ̀kú Ọ̀bàrà (òyèkú pàbàlà)
Post a Comment