Friday, December 29, 2023

Alaye nipa ilu Gudugudu

SHARE
Kosi ba se fe so nipa iyan gidi ti n jo ni lowo lai so nipa isu iyan re, asoku alaye ni yoo si je lai menu ba odo to gunsu ko to diyan.Nje eyin mo wi pe, ko sologbon aye kan ti yoo so nipa ogi lai menu ba agbado yanga. Awon Yoruba lo si wi pe, kagbado to deko, yangi ni won lo papo ko to dounje.

Kosi ba se fe so nipa orin , onkorin, lai menu awon eroja orin kiko ati bi a se sada orin to dun leti omo araye. Ojo aboki ti pe ni sabo, orin kiko si ti wa laye lati igba tomo eda ti wa loke erupe.
 Orisiirsii awon onkorin ni won si ti lo samooni saaju asiko olaju to wole de. Iru awon ohun elo orin wo ni won lo? Sebi ki agbado to daye, ohun kan ni adiye nje. Ki won to gbe penti de ni Yoruba ti n le laali.


Ki awon oyinbo to gbe jaasi de, awon baba nla wa ni ti n lo oniruuru ilu pelu awon eroja orin kiko loniranran, eleyii ti pupo won si wa titi di akoko yii.

Sugbon sa, ti a ba n so nipa orin, kini orin je? Kini won peni Orin gan-an?

Orin je ohun enu tabi ohun ti eroja orin fo jade, eleyii ti a gbe kale ni ona ara lati dun leti nipa sise afiahan ero okan wa.


Awon kan tun se alaye orin gege bi orisii ise ona kan pataki. A tun le pe ni amuludun eleyii ti a se nipa apapo akojopo ohun ni ona ti awon eniyan fe tabi ni ona ti yoo mu awon eniyan nife sii.


Awon ojogbon kan tile gba wi pe, ko si itunmo kan pato ti a le fun orin eleyii to le kogoja gege bi itunmo kan to pegede ju lo.

Won ni orin je ise ona kan pato, bakan naa ni ero onikaluku nipa ohun ti orin je naa tun je ohun kan ti a ko gbodo foju pare. Eyin tun mo si wi pe, ohun ti enikeni gba gege bi orin naa le duro bi orin gege bi ero eni naa. Sebi ohun to koju seni kan eyin lo ko si eloomii.


Ni ile Yoruba, orisiirisii awon orin igba iwase bi were, sakara, dadakuada, apala, senwele, fuji, ajisari, waka ati juju, lonii awon ohun elo orin kan pato to ma n je koko ninu awon ohun elo orin won.


Sugbon lonii, a ma se agbeyewo orisii ilu kan ti n je gudugudu. GUDUGUDU!


Gudugudu je orisii ilu kan eleyii to wopo laarin awon eya Yoruba ti won gbe ni guusu iwo oorun orilede Naijeria.

 Ti ba n so nipa ohun elo orin kiko, Gudugudu si je okan pataki laarin awon eya ilu dundun. Ti iya ilu ohun omele ba n ro polapola, atileyin kekere ko ni gudugudu n se fun won lati gbe adun orin won yo.

Eleyii ja si wi pe, lode orin taaba ti ri dundun, gudugudu kii saba gbeyin nibe.


Irisi gudugudu dabi abo ikeemu olobiripo. Oju kan pere ni gudugudu n ni eleyii ti a fi awo eran de lori.

 Awo eran yiyi, koboko teere penpe meji bayii ni won si fi n lu orisii ilu ti a ma mo si gudugudu. Gbigbe ni onilu ma n gbe gudugudu korun bi alakorun ni awon akoko ti to ba fi kokoro kanju awo. Poroporo ni oku eruwe yoo si ma ma fohun bi eniyan gidi.Ko wa si iru ara ti a ko le fi gudugudu da bi awon ilu yoku, onilu le fi gudugudu soro ti ohun ti n so yoo si han kedere feni to leti ilu. Lara awon orisii orin ti won ti maa n saba lo gudugudu ni apala, fuji, juju ati bbl.

This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647).For the following:::

IFA consultation and Divination

Egbe Orun initiation

Appeasement of Egbe Orun

Yes and No questions

Feeding of Ori (inner head)

Feeding of ORISA

IFA INITIATION

Solutions to Problems

Source: https://www.orisa.com.ng

SHARE

Author: verified_user

AJE NLA Spiritual Traveller | OLOBATALA | OMO OLOKUN, OMO ORISA | BABALAWO OMO ORUNMILA | CEO www.orisa.com.ng | +2347031178647 For IFA Consultation, Divination, Yes / No questions , spiritual guidance, Dream interpretation etc whatsapp https://wa.me/2347031178647

0 $type={blogger}: