IPOLOWO OJA
Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta.
ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA:
(1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja
(2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja .
(3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA
Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri.
(i) ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl
(ii) ITO,:WO :Yoruba ni itowo ni adun obe”Eyi ni ki onibara to die wo ninu ohun ti o f era.Awon nnkan ti a le towo ni gaari,epo.aadun abbl
(iii) ISIWO:Eyi ni ki a si nnkan ti a f era wo lati rii bi o se ri tabi gbo oorun re ti o n ta nnkan didi maa n si wo.
(iv) OJA AWIN:Oloja le fun onibara re ni anfaani lati wa sanwo oja ti o ran i ojo miran.Awin ni ohun ti a r alai san owo.
|
NNKAN TITA |
ONA IPOLOWO |
|
1 |
Agbado sise |
Langbe jina o Oruku ori ebe Ibe oni o sooro |
|
2 |
Agbon |
Agbon gbo keke bi obi |
|
3 |
Efo |
E’refo,e’sebe o Aje b’oko rerin in ofofo |
|
4 |
Gaari |
Gaari oloyo de o Ayangbe gaari o |
|
5 |
Iyan |
Iyan-re,obe re Ewoju obe e muyan Kengbe’yan kolobe |
|
6 |
Ewa sise |
Lamuluke Muke jina o |
|
7 |
Moimoi |
Moimoi epo Moimoi elede Oole mi rodo |
|
8 |
Eko |
E jeran eko Ori bi ike Paabo eko o Oniyangi de o |
|
9 |
Amala |
Aroyi amala Mo ro oyi o |
|
10 |
Eja tutu |
Gbetu omi akerese Ki I dun l’odo B’o de’le a do’yin |
|
11 |
Iresi |
Ofe niresi,eran lowo |
|
12 |
Isu sise |
Isu epo O tu se’po muye |
|
13 |
Oyin-igan |
Oyin-igan re e |
|
14 |
Elewedu |
Elewedu t’oko de E maa bo |
|
15 |
Guguru ati epa |
Guguru re e Epa re e. |
|
16 |
Robo |
Robo egba re e |
|
17 |
Egbo |
O n yorii joo O yoruku lala |
|
18 |
Isana |
Isana ale o Fere ni jo Onisana n relee maa baa daro |
|
19 |
Epo-pupa |
Ere’po, e se’be o. |
|
20 |
Epo oyinbo |
Arokun epo oyinbo |
|
21 |
Ila |
Ee ko’la ore, Ila ede re e o |
|
22 |
Ogi |
Ologi de o |
|
23 |
Ekoogbona |
E dako mu o |
|
24 |
Eba |
Kengbe eba Eba re e,eran re e |
|
25 |
Adiye |
Ee l’adiye ta bi,ara onile |
IPOLOWO OJA NI ODE-ONI
Itesiwaju ti de ba ipate ati ikiri oja ni ode-oni.Oniruuru ona igbalode ni ipolowo oja n gba waye.
Apeere:
(1) IPOLOWO OJA NI ORI REDIO:Oniruuru ete ni won pa ni ori redio lati polowo oja.
(2) IPOLOWO NI ORI AMOHUNMAWORAN:Awon oloja n polowo ni ori ero telifi son.
(3) IPOLOWO NINU IWE IROYIN:Awon oloja maa n polowo oja won ninu iwe iroyin ojoojumo.
(4) LILO PATAKO OJU POPO:Awon ontaja yoo le aworan oja mo patako feregede ni oju titi lati polowo.
(5) IWE ILEWO PINPIN TABI LILE MO ARA OGIRI:Awon ontaja le ha iwe ilewo fun awoneniyan,won le fon ka aarin ilu tabi le won mo ara ogiri eba ona tabi oja.
(6) PIPATE OJA NINU ILE ITAJA: Awon ontaja maa n pate oja sinu soobu,ti won yoo le iye owo oja mo won lara
(7) IKOPA NINU IPATE OJA: Eyi maa n waye ni awon ilu nla-nla bi Eko,Kaduna, ati bee bee lo lekan lodun
(8) LILO ERO GBOHUNGBOHUN :Awon ontaja n lo gbohungbohun ni ori keke,alupupu tabi motolati polowo oja won.
ANFAANI IPOLOWO OJA;
1) O maa n je ki won mo ohun ti a n ta
2) O maa n je ki oja ya ni tita.
3) O maa n je ki a ni onibara pupo.
4) O maa n mu ki eto oro aje gbera soke.
5)O maa n polongo oja jakejado ilu tabi agbegbe.
Source of Article: https://www.orisa.com.ng
This Article was written by AJE NLA the son of OBATALA +2347031178647.
You can contact AJE NLA for ...
ODU OBATALA Consultation
Egbe Orun INITIATION
OSUN Initiation
Begging of the elders
Feeding of ORISA OSUN, OBATALA, Egbe Orun, TAJENIKARO (AJE that fights for your wealth), AJELETI (AJE from IYAAMI), ONIMERE (for all Emere), AJASORO (Revenge and door opener), AJE OLOKUN, ESU, ELEGBA (Justice and way opener) etc.
Discover more from ORISA BLOG
Subscribe to get the latest posts sent to your email.