IWA OMOLUABI ATI ISORO TO N KOJU RE.
Ni ile Yoruba iyi ni lati pe enikeni ni omoluabi. Omoluabi ni eni ti iwa re dara pupo, to n hu iwa rere ati iwa to ye ninu ile, ijo, egbe ati laaarin ilu.
Owo-nini, ogbon-inu tabi gbajumo ko so ni di omoluabi. Yoruba won ni iwa rere leso eniyan.
AWON IWA TO N MU NI JE OMOLUABI
OOTO SISO : omoluabi gbodo je olododo to se e fi okan tan ni gbogbo igba, omoluabi ko je huwa abosi, ireje, puro tabi gba ohun olohun mo ti.
IBOWO FUN AGBA: omoluabi ni eni to ni owo ati iteriba fun agbalagba ati gbogbo awon ti o ju u lo. Omoluabi eniyan maa n teriba fun aba tabi ogbon agba, bee ni k I lodi si imoran won. Ni ile Yoruba , a n bowo fun awon eniyan ti won ba wa ni ipo, bii Oba, Ijoye ati bee bee lo.
IWAPELE ATI SUURU : omoluabi gbodo je eni ti ki I binu odi, bee ni o gbodo je eni to ni suuru, tI oro enu re maa n je iwuri ati iyanilori. O je eni ti o ma se ohun gbogbo pelu irele.
IKINI : ibi ikini ni a ti n mo ojulowo eniyan. Omoluabi a ma ki ni pelu iyesi ati owo. O mo ikini ati idahun ti o ye fun igba, akoko, ise ati isele.
AFORITI : Aforiti tabi ifarada je okan Pataki ninu abuda eda. Omoluabi gbodo ni ifarada, nitori ko si eda naa ti ko le ni isoro. Bi isoro ba de omoluabi gbodo ni okan lati bori isoro re
BIBI IRE : omoluabi yoo mo asiko to ye lati wole sun, omo ti won bi ni ile ire, ti won ko to gbeko, ko je ba won rin ni oru. Yoruba ni ijakumo ki I rinde osan, eni a biire kan ki i rin ru.
NINI IFE ENIKEJI : Ife se Pataki bee ni o se koko, ife ani denu ni a wi . Bi eniyan ba ni isoro, omoluabi yoo gbiyanju lati ba mu isoro naa kuro tabi din ku, bi a ba ri eniyan ti o n se lodi si ohun to ye tabi ni ewu, ojuse omoluabi ni lati kilo fun un.
OHUN RERE : oro rere gbodo maa tie nu wa jade ni gbogbo igba. Omoluabi gbodo mo oro to to lati so lawujo
IWA IGBORAN : Omoluabi ki i se aigboran si oro agba tabi se ori kunkun. Eni ti a ba n bawi ti o ba warunki, yoo parun lojiji lai ni atunse.
OJUSE OMOLUABI
1. OJUSE OMOLUABI SI OBI
2. OJUSE OMOLUABI SI IJOBA/AWUJO
3. OJUSE OMOLUABI SI OMONIKEJI
Source of Article: https://www.orisa.com.ng
AJE NLA the son of OBATALA is registered with CAC No: 8022733
This Article was written by AJE NLA the son of OBATALA with +2347031178647.
You can contact AJE NLA for ...
ODU OBATALA Consultation
Egbe Orun INITIATION
OSUN Initiation
Begging of the elders
Feeding of ORISA OSUN, OBATALA, Egbe Orun, TAJENIKARO (AJE that fights for your wealth), AJELETI (AJE from IYAAMI), ONIMERE (for all Emere), AJASORO (Revenge and door opener), AJE OLOKUN, ESU, ELEGBA (Justice and way opener) etc.
Discover more from ORISA BLOG
Subscribe to get the latest posts sent to your email.