Showing posts with label oriki. Show all posts
Showing posts with label oriki. Show all posts

Wednesday, March 20, 2024

ORIKI OFFA

ORIKI OFFA

YORUBA – ORIKI OFFA (THE COGNOMEN OF THE OFFA PEOPLE)
Short Version:
Iyeru-Okin,

 Omo Olofa Mojo,


 Omo Olalomi,


 Omo abisu Joruko ,


 ijakadi loro toffa toffa, 


Ija kan ijakan ti won nja lofa lojosi,

 Olalomi oju talose, 

Osoju ebe lala, 


O si soju poro ninu oko, Ibasoju oloko, 


iba lawon, Omo ‘laare, Omo bu re, ikan o gbodo ju kan,


 Bi kan ba ju kan nile olofamojo ogun lon’da ni ile baba wan, 


Omo omaka, Omo osa oje ba mi ki anomo. Omo olalomi ni mori, 


Mo dasa lami lapa, Iyeru okin ni mori, Mo dasa lami lobe, 


Mi o pe e mo lami sugbon, E mo je ko jinle lapa mi, Ijakadi loro ofa.
Long Version:


Ede okin olofa mojo, olofa omo ola nlomi ab’isu joko ijakadi loro Offa, ija peki abe owula, bi ko ba se oju ebe l’Offa, as óju poro l’oko, iba soju oloko iba la won, osoju agunmona l’Offa , O soju agbele yarara, o soju aporuba ka ‘ko, kinni se kagun-kakanrun ni ile oba, 


oka ni se kagun kankanrun, Agbado ni agun-mona l’Offa, Eree ni agbele yarara, isu ni aporubu ka ‘ko, 


omo odi meta mete meta me ti nbe l’Offa mojo, odi iwaju ti olusan, t’ehin ni se ti olumiran, t’arin gungun ni se ti olugbenise omo ayejin,
 omo odo meta meta ti ntun nbe l’Offa mojo, okan ni apa erinla boo un ki oun dókun, okan ni apa agbo boo un ki oun d’osa,
 okan ni ki apa akuko gagara boo un ki oun di agunloko l’Offa oba ni okookan Offa ti t’agbo ra,
 ododo won ti to erinla pa sugbon ni okan ba d’okun, ti okan ba d’osa nibo ni ako omo yebiye wonyisi.
 Eyi ti won wapa akuko ganga boo a ni owa di agunloko l’Offa olofa omo la ki Offa kun tele, olalomi ede okin olofa mojo Olofa Omo laare ki o dogba, okan ko gbodo ju kan bi okan ba ju kan, 
oba ni ko won roro, oba ko wa ri ti awa d’iran peki mob a odofin dimu, mose ojomu Karin, mo fi ehin saawo ra’le l’Offa o m’aka Arijasoro, olalomi lo laare. Offa o m’aka egun wole l’Offa to ju ti omo okuta meta nsese, okan ko mi lese okansemi pele, okan semi nrora, Okan n’gbati emi mona , kinni mo wade ilu ete okan n’gbati emi ko mona kinin mo wa de ilu ero Okan n’gbati emi mona ,
 kinni mo wa de ilu awon-won ni ile olalomi ti omi ti won ti oju lo Ede Okin timo ri okin bamuiti mofi abata sin ese l’Offa ti mo wari abelenje boju mo la k’Offa okun keekee Aral ale, olalomi omo orubo nla ti osubu l’aro papa ni ohun bata, oki mi o nla mi, olalomi tani osehun ninu ara won ileyi ko gbaye, a ko lo si loffa nigbati iloffa o gba wa a ko lo s’Offa oro nigbati Offa oro o gba wa, 

a ko los’Offa irese nigbati Offa irese ko gba wa, ako losi igbolutu nigbati igbolutu ko gba wa mo, 
a tun pada si Offa Eesun nigbati Offa eesun o gbawa mo ni awa kowa si Offa Arinlolu olofa se pele o aro ko ya bumu, 


Ede olele aro ko ya buwe Ede olele aro ko ya buboju igun ni a rini a dasa geru, 


Akala nia rini a sasa l’edo olofa imole ni arin ni a wa dasa lami labe lapa se olofa lo ni omo ,
 ko si Eku ti oju Offa o di oyo olofa ni oni omo gbengbeleku ni ara yoku nsan ni nwon ki olalomi iyeru okin.
ORIKI IJEBU

ORIKI IJEBU

YORUBA – ORIKI IJEBU (THE COGNOMEN OF THE IJEBU PEOPLE)Ijebu omo alare,

omo awujale,

omo arojo joye,


omo alagemo ogun woyowoyo,

omo aladiye ogogomoga,

omo adiye balokun omilili,


ara orokun,


ara o radiye,


omo ohun seni oyoyonyo,

oyoyo mayomo ohun seni olepani,

omo dudu ile komobe se njosi,

pupa tomo be se okuku sinle,

omo moreye mamaroko,

morokotan eye matilo,

omo moni isunle mamalobe,

obe tin benile komoile baba tobiwan lomo,

Omo onigbo ma’de,
omo onigbo mawo mawo,


omo onigbo ajoji magbodowo,
ajoji tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.

Ijebu omo ere niwa,

omo olowo isembaye,
towo kuji to dode,

koto dowo eru,

koto dowo omo.
Orisa jendabi onile yi,

niwan finpe igba ijebu owo,
kelebe ijebu owo,
ito ijebu owo, dudu ijebu owo,

pupa ijebu owo,
kekere ijebu owo,

agba ijebu owo.

Ijebu ode ijebu ni,
ijebu igbo ijebu ni,

ijebu isara ijebu ni,
ayepe ijebu,
ikorodu ijebu ijebu noni,

Ijebu omo oni Ile nla,
Ijebu omo alaso nla!
Ajuwaase ooo!


ORIKI AINA

ORIKI AINA

ORUBA – ORIKI AINA (ENI TI AKO GBODO NA)(The panegyrics of the Yoruba female child with the umbilical cord woven around her neck at birth)


Aina orosun

Aina oroyinyin

O ni guda ibi

A ji nawo ara

Aina keke legun

Eni a be be be ko to seso


Tibii ko je ko r’oko ni


O lepo ni kolo


O lagbagba nibawo


O l’adie l’aba


A ji b’oba re

Egungun gbangba n’isasun Obe

A ji j’eran to tobi.

Aaaaaaina oooooo!
ORIKI OJO

ORIKI OJO

 ORIKI OJO


(The panegyrics of the Yoruba male child born with the umbilical cord woven around his neck at birth)

Ojo olukuloye,

Ojo yeuge,

Alagada ogun

Ojo ja loja o dele k’oy iyan sile

Igbe kike ni bieye

Ojo ko si nile

Omo adie dagba


Iba wan anile yio ti pa iyare je  
ORIKI IWO

ORIKI IWO

ORIKI IWO (THE PANEGYRIC OF IWO PEOPLE)
Iwo olodo oba,

Omo ateni gbola, teni gbore nile odidereOmo oba to lu gberinAfiporo je omo to lu gberin gberin

Iwo ti ko nilekun beni koni kokoro,


Eru wewe ni won fi n dele

Eru ko gbodo je m’ogberin,

Iwofa ko gbodo je mogbede

Omo bibi inun won ni je m’oderin

Bi wo kola biwo kolowo lowo,

Eru ti n se mi ni rami ta mi to mi ni temi o jare

Iwo lomo Olola ti n san keke,

Iwo lomo oloola ti n bu abaja

Agbere ni wa won ki gbowo Ila lowo awa

Eyin lomo ara eru ke omo,

Omo ara eru bere eni

Omo araya le ki omo tode.

Iwo ilu Alfa

Iwo todidere pepepe tenure te k’oroyin


Wednesday, March 6, 2024

Oriki Ikoyi Eso

Oriki Ikoyi Eso

Here is an Oriki for Ikoyi Eso in Yoruba language:
“Ikoyi eso omo owa,omo aro, omo ase, omo Alaketu.Omo ilu omi, omo ilu omi tutu.Adifa fun ewelewele, ti n lo re omo Ikoyi eso.
Won ni ki n ta ori loju ogun,
won ni ki n wa ni ibeji ni.
Ikoyi eso ni won ni ki n pe ni won ni ka toju ona,
bi a ba fi oju ona we won a fi igbala da won.
Awon to gba eyin eranko ni won ni ki n ka ara won mu,
bi a ba fi ara won mu won a fi oju ona we won a fi igbala da won.”

Monday, March 4, 2024

Oriki Ira (Oriki ilu Ira)

Oriki Ira (Oriki ilu Ira)

Oriki Ira
Ira, Laaru Osin, Onira Laage, Iloko Omo Arelu,


Ma relu mi mo, Ori Olori ni k Oya o maa wa kiri Lagbedajo,


Omo Afaja wusi oku ni popo Ira,Omo lele bi otutu


Gingingin loye mu ni le baba won.


Ki iwo yala,kemi yala kere pade L’ajogbori


Ajogborini mi , mi o jo gba eko ototo eyan ni mojo


Gba loro kekere Iloko, oti mu da o die le kekere Iloko,


O ti muda Odi ero Iloko timuda odi iberu eru omo ajoba,


Lo lele agba Iloko nawo nase sile oni ori laabe ni abe se ni Iloko oro


Arelu eyo omo abatabutu oju Okun Olere, Ehin okun ose tu ni kengbe,


Abata butu oju omi kohu koriko .
WHAT IS ORÍKÌ?

WHAT IS ORÍKÌ?

WHAT IS ORÍKÌ?
Oriki is an important and cultural, but unwritten (oral) genre of Yoruba literature that is usually used in praise singing. 
The Yoruba people have very rich cultural oral literature, oriki is one of them.

Monday, January 22, 2024

ORIKI ORI

ORIKI ORI

ORIKI ORI


Ori Onise Apere Atete gbeni ju Orisa 

Ori atete niran 

Ori lokun 

Ori nide 

Ko si Orisa ti dani gbe leyin Ori eni 


Ori ni seni ta a fi dade owo 


Ori ni seni ta a fi tepa ileke woja 


Ori ni seni ta a fi lo mosaaji aso oba 

Ori gbe mi 

Ori la mi 

Ori ma pada leyin mi 
Translation 

Ori, the competent Creator Apere


He who is faster in aiding one than the Orisa


He who instantly remembers his devotee


Ori is valuable


Ori is jewelry


No Orisa can favour one without the consent of one’s Ori


It is Ori that aids one for one to be crowned of money


It is Ori that bless one for one to be using beaded walking stick even to the market


It is Ori that bless one for one to be using valuable cloths


Ori, please, support me


Ori, please, bless me

Ori, please, never turn against me.

Saturday, January 6, 2024

Oríkì Onílù

Oríkì Onílù

Oríkì OnílùỌmọ afi gúdúgúdú ṣ'ọlá,Ọmọ afi dùndún ṣ' ọrọ̀,Ọmọ Àyándìran.Bí baba mi ti ńlù,


Bẹ́ẹ̀ ni ṣaworo ìlù rẹ̀ ńdún,Ọmọ alùlù gbowó.
Baba mi ni ń fi dùndún
Sọ̀rọ̀ bí ènìyàn láàrin ìlú,
Ọmọ afi gúdúgúdú fọhùn arò,
L'áàfin Ọba

Friday, December 29, 2023

ORIKI IKA MEJI

ORIKI IKA MEJI

ORIKI IKA MEJI
(Invocation for Good Fortune)

Ika Meji, Ika Meji, Ika Meji,


The Controller, the Controller, the Controller,


mo be yin, kie ka ibi kuro lona fun mi lode aye.

I beg you, remove all obstacles wherever I go in the world.

Kie bami ka’wo Iku. Arun ejo ofo ofo efun edi apeta oso.
Prevent Death disease litigation, loss and hexing. Prevent harm from those who work hexes.

Aje at awon oloogun buburu gbogbo. Ika Meji. Ase.

Prevent all forms of hex against me. The Controller. May it be so.


Thursday, December 28, 2023

ORIKI OKANRAN MEJI

ORIKI OKANRAN MEJI

ORIKI OKANRAN MEJI

(Invocation for Good Fortune)

Okanran Meji, Okanran Meji, Okanran Meji,

The Beater if Sticks on Mats, The Beater if Sticks on Mats, The Beater if Sticks on Mats,


Mo be yin, ki e jeki oran ibanje maa kan gbogbo awon ti, o ndaruko mi ni ibi ti won nsepe so mi, ti won nsoro buburu si oruko mi, awon ti nbu mi, ti won nlu mi ti won, ngb’ero buburu si mi.

I beg you, let all my enemies meet adversity, that sorowful things will be in their road, those that are calling my name in evil, those who are cursing me, those who are abusing me, those who are wishing bad things against me.


Okanran Meji, Okanran Meji, Okanran Meji,  kiesi ilekun ori rere fun mi ati beebee. Ase.


The Beater if Sticks on Mats, The Beater if Sticks on Mats, The Beater if Sticks on Mats, open the door of good luck and prosperity for me. May it be so.

_____________________________


ORIKI OYEKU MEJI

ORIKI OYEKU MEJI

ORIKI OYEKU MEJI(Invocation for Good Fortune)
Oyeku Meji, Oyeku Meji, Oyeku Meji leemeta

The Averter of Death, the Averter of Death, The Averter of Death, I call you three times.

Mo be yin, bi iku ba sunmo itosi kie bami ye ojo iku fun.

I beg you, if Death is coming, help us to avert it.

Si ehin Ogun tabi ogorun odun, tabi bi iku ba nbo kie bami yee si ehin ogofa.

For all the years that I will be on the Earth, avert my death until the pre-ordained time of passing.

Odun tiatibi mi sinu aye kie bami ye ojo iku fun ara mi ati awon omo mi ti mo bi.

Avert Death for all my children and avert Death for all those I include in my prayers.

Kiamaku ni kekere, Kiamaku iku ina, kiamaku iku oro, kiamaku iku ejo, kiamaku sinu omi, Ase.

May they not die young, may they not die in fire, may they not die in tragedy, may they not die in shame, may they not die in water. May it be so.


ORIKI IROSUN MEJI

ORIKI IROSUN MEJI

ORIKI IROSUN MEJI

(Invocation for Good Fortune)

Irosun Meji, Irosun Meji, Irosun, Meji,

The Sounding Osun, the Sounding Osun, the Sounding Osun

Mo be yin, kie jeki awon omo-araye gburo, mi pe mo l’owo l’owo pe mo niyi, pe mo n’ola, pe mo bimo rere ati beebee.

I beg you, let the whole world hear of me, that I am rich, that I have honor, that I have prestige, that my children will be good.

Kie jeki won gbo iro mi kaakiri agbaye, Irosun Meji. Ase.

Let them hear around the world that I am a good and blessed person. The Sounding Osun. May it be so.


ORIKI IWORI MEJI

ORIKI IWORI MEJI

ORIKI IWORI MEJI


(Invocation for Good Fortune)
Iwori Meji, Iwori Meji, Iwori Meji,

The Deep Seer, the Deep Seer, the Deep Seer,

Mo be yin ki a ffoju re wo mi, ki awon omo araye lee maa fi oju rere wo mi. Kie ma jeki nsaisan ki nsegun odi ki nrehin ota.


I beg you to look upon me with good eyes, so that the world will be favorable to me and so that I will be free from illness. Let me overcome my enemies.

Ki e ma jeki awon iyawo mu ya’gan, takotabo ope kiiya-agan. Iwori Meji. Ase.

Let my wives be fertile, just as the male and female palm trees are never barren. the deep seer. May it be so.


Wednesday, December 27, 2023

ORIKI ODI MEJI

ORIKI ODI MEJI

ORIKI ODI MEJI
(Invocation for Good Fortune)

Odi Meji, Odi Meji, Odi Meji,

The Seal, the Seal, the Seal,

Mo be yin, kie bami di ona ofo, kie bami di odo ofo, kie bami di ona ejo, kie bami di ona ibi, kie bami di ona Esu,

I beg you, close the way of losses to me, close the way of losses for my children, my mate and my family, close the way of litigation against me, close the way of negativity against me, close the way of disruption from the Spirit of the Trickster.

Ni nri’di joko pe nileaye. Kiema jeki nba won ku – Iku ajoku.

Let me sit quietly in the world. Let me not die in an epidemic.

Okan ewon kiike.

One link in a chain will not make a lock.

Kie se – Odi agbara yi mi ka, Ki owo mi ka’pa omo araye bi omo Odi tiika’lu. Ase.

I pray that you will rally around me, in the same way that we put a garden around a yard. May it be so.
ORIKI OWONRIN MEJI

ORIKI OWONRIN MEJI

ORIKI OWONRIN MEJI
(Invocation for Good Fortune)


Owonrin Meji, Owonrin Meji, Owonrin Meji,


The Reversed Head, The Reversed Head, The Reversed Head,
Mo be yin, ki eso ibi de rere fun mi ni gbogbo ojo aye mi, ki emi-re s’owo, ki emi mi gun ki ara mi kiole, ki nma ri ayipada di buburu lojo aye mi ati beebee. Ase.I beg you, turn evil to good throughout all my days on earth, that I might be rich, that all my life will be lengthened and that my health will always be good, and that turning from good to bad may not reach me in all my days in the world. May it be so.Owonrin Meji. Ase.

The Reversed Head. May it be so.


ORIKI OBARA MEJI

ORIKI OBARA MEJI

ORIKI OBARA MEJI
(Invocation for Good Fortune)


Obara Meji, Obara Meji, Obara Meji,The Resting and Hovering One, The Resting and Hovering One, The Resting and Hovering One,


Mo be yin, ki e si’na aje fun me, ki awon, omo araye wa maa bami, ra oja ti mo ba niita wartawara, ipeku Orun e pehinda l odo mi. Ibara Meji de at beebee. Ase.I beg you, open the way to wealth for me, that the whole world will want the products of my work, that untimely death will pass me by, the Resting and Hovering One has come. May it be so.
_______________________________


ORIKI OGUNDA MEJI

ORIKI OGUNDA MEJI

ORIKI OGUNDA MEJI(Invocation for Good Fortune)

Ogunda Meji, Ogunda Meji, Ogunda Meji,

The Creator, The Creator, The Creator,

Me be yin, kiedai ni’de Arun Ilu ejo egbese ati beebee, ki e d a’ri ire owo,

I beg you, release me from the tie of Death, release me from the tie of Misfortune, direct me towards the good fortune of Abundance,
ise oro omo ola ola emigigun, aralile ati beebee s’odo mi,


direct me towards the good fortune that comes from good and fruitful children, direct me towards the good fortune of honor, prosperity, good health and long life,

Kie da mi ni abiyamo tiyoo bimo rere ti won, yoo gb’ehin si-sinu aye ati beebee.

let me be known as a parent who produces good children, who will stand behind me, follow my guidnace and bury me at the end of my life.


Ogunda Meji.  Ase.

The Creator. May it be so.


ORIKI OSA MEJI

ORIKI OSA MEJI

ORIKI OSA MEJI(Invocation for Good Fortune)


Osa Meji, Osa Meji, Osa Meji,

Run-Away, Run-Away, Run-Away,

mo be yin, kie jeki ndi arisa-ina, akotagiri ejo fun awon ota,

I beg you, let me be as a fire from which people flee, or as the snake that is greatly feared to its enemies,

Kieso mi di pupo gun rere, ki’mi r’owo san owo ori, kimi r’owo san awin Orun mi ati beebee. Osa Meji. Ase.


Let me blessed for good, that I will always have the money to pay my debts, may I always do good things in the world. Run-away. May it be so.