Showing posts with label oriki. Show all posts
Showing posts with label oriki. Show all posts

Wednesday, March 20, 2024

ORIKI OFFA

ORIKI OFFA

YORUBA – ORIKI OFFA (THE COGNOMEN OF THE OFFA PEOPLE)
Short Version:




Iyeru-Okin,

 Omo Olofa Mojo,


 Omo Olalomi,


 Omo abisu Joruko ,


 ijakadi loro toffa toffa, 


Ija kan ijakan ti won nja lofa lojosi,

 Olalomi oju talose, 

Osoju ebe lala, 


O si soju poro ninu oko, Ibasoju oloko, 


iba lawon, Omo ‘laare, Omo bu re, ikan o gbodo ju kan,


 Bi kan ba ju kan nile olofamojo ogun lon’da ni ile baba wan, 


Omo omaka, Omo osa oje ba mi ki anomo. Omo olalomi ni mori, 


Mo dasa lami lapa, Iyeru okin ni mori, Mo dasa lami lobe, 


Mi o pe e mo lami sugbon, E mo je ko jinle lapa mi, Ijakadi loro ofa.




Long Version:


Ede okin olofa mojo, olofa omo ola nlomi ab’isu joko ijakadi loro Offa,



 ija peki abe owula, bi ko ba se oju ebe l’Offa, as óju poro l’oko,



 iba soju oloko iba la won, osoju agunmona l’Offa , 



O soju agbele yarara, o soju aporuba ka ‘ko, kinni se kagun-kakanrun ni ile oba, 


oka ni se kagun kankanrun, Agbado ni agun-mona l’Offa, 



Eree ni agbele yarara, isu ni aporubu ka ‘ko, 


omo odi meta mete meta me ti nbe l’Offa mojo, 



odi iwaju ti olusan, t’ehin ni se ti olumiran, t’arin gungun ni se ti olugbenise omo ayejin,




 omo odo meta meta ti ntun nbe l’Offa mojo,



 okan ni apa erinla boo un ki oun dókun, okan ni apa agbo boo un ki oun d’osa,




 okan ni ki apa akuko gagara boo un ki oun di agunloko l’Offa oba ni okookan Offa ti t’agbo ra,




 ododo won ti to erinla pa sugbon ni okan ba d’okun, ti okan ba d’osa nibo ni ako omo yebiye wonyisi.




 Eyi ti won wapa akuko ganga boo a ni owa di agunloko l’Offa olofa omo la ki Offa kun tele, 



olalomi ede okin olofa mojo Olofa Omo laare ki o dogba, okan ko gbodo ju kan bi okan ba ju kan, 




oba ni ko won roro, oba ko wa ri ti awa d’iran peki mob a odofin dimu, mose ojomu Karin, 



mo fi ehin saawo ra’le l’Offa o m’aka Arijasoro, olalomi lo laare. 



Offa o m’aka egun wole l’Offa to ju ti omo okuta meta nsese, 



okan ko mi lese okansemi pele, okan semi nrora, Okan n’gbati emi mona , 



kinni mo wade ilu ete okan n’gbati emi ko mona kinin mo wa de ilu ero Okan n’gbati emi mona ,




 kinni mo wa de ilu awon-won ni ile olalomi ti omi ti won ti oju lo Ede Okin timo ri okin bamuiti mofi abata sin ese l’Offa ti mo wari abelenje boju mo la k’Offa okun keekee Aral ale, 



olalomi omo orubo nla ti osubu l’aro papa ni ohun bata, oki mi o nla mi, 



olalomi tani osehun ninu ara won ileyi ko gbaye, a ko lo si loffa nigbati iloffa o gba wa a ko lo s’Offa oro nigbati Offa oro o gba wa, 





a ko los’Offa irese nigbati Offa irese ko gba wa, ako losi igbolutu nigbati igbolutu ko gba wa mo, 




a tun pada si Offa Eesun nigbati Offa eesun o gbawa mo ni awa kowa si Offa Arinlolu olofa se pele o aro ko ya bumu, 


Ede olele aro ko ya buwe Ede olele aro ko ya buboju igun ni a rini a dasa geru, 


Akala nia rini a sasa l’edo olofa imole ni arin ni a wa dasa lami labe lapa se olofa lo ni omo ,




 ko si Eku ti oju Offa o di oyo olofa ni oni omo gbengbeleku ni ara yoku nsan ni nwon ki olalomi iyeru okin.
ORIKI IJEBU

ORIKI IJEBU

YORUBA – ORIKI IJEBU (THE COGNOMEN OF THE IJEBU PEOPLE)



Ijebu omo alare,





omo awujale,





omo arojo joye,






omo alagemo ogun woyowoyo,





omo aladiye ogogomoga,





omo adiye balokun omilili,






ara orokun,






ara o radiye,






omo ohun seni oyoyonyo,





oyoyo mayomo ohun seni olepani,





omo dudu ile komobe se njosi,





pupa tomo be se okuku sinle,





omo moreye mamaroko,





morokotan eye matilo,





omo moni isunle mamalobe,





obe tin benile komoile baba tobiwan lomo,





Omo onigbo ma’de,




omo onigbo mawo mawo,










omo onigbo ajoji magbodowo,




ajoji tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.





Ijebu omo ere niwa,





omo olowo isembaye,




towo kuji to dode,





koto dowo eru,





koto dowo omo.




Orisa jendabi onile yi,





niwan finpe igba ijebu owo,




kelebe ijebu owo,




ito ijebu owo, dudu ijebu owo,





pupa ijebu owo,




kekere ijebu owo,





agba ijebu owo.





Ijebu ode ijebu ni,




ijebu igbo ijebu ni,





ijebu isara ijebu ni,




ayepe ijebu,




ikorodu ijebu ijebu noni,





Ijebu omo oni Ile nla,




Ijebu omo alaso nla!




Ajuwaase ooo!


ORIKI AINA

ORIKI AINA

ORUBA – ORIKI AINA (ENI TI AKO GBODO NA)



(The panegyrics of the Yoruba female child with the umbilical cord woven around her neck at birth)






Aina orosun





Aina oroyinyin





O ni guda ibi





A ji nawo ara





Aina keke legun





Eni a be be be ko to seso






Tibii ko je ko r’oko ni






O lepo ni kolo






O lagbagba nibawo






O l’adie l’aba






A ji b’oba re





Egungun gbangba n’isasun Obe





A ji j’eran to tobi.





Aaaaaaina oooooo!
ORIKI OJO

ORIKI OJO

 ORIKI OJO


(The panegyrics of the Yoruba male child born with the umbilical cord woven around his neck at birth)





Ojo olukuloye,





Ojo yeuge,





Alagada ogun





Ojo ja loja o dele k’oy iyan sile





Igbe kike ni bieye





Ojo ko si nile





Omo adie dagba






Iba wan anile yio ti pa iyare je  
ORIKI IWO

ORIKI IWO

ORIKI IWO (THE PANEGYRIC OF IWO PEOPLE)




Iwo olodo oba,





Omo ateni gbola, teni gbore nile odidere







Omo oba to lu gberin







Afiporo je omo to lu gberin gberin





Iwo ti ko nilekun beni koni kokoro,






Eru wewe ni won fi n dele





Eru ko gbodo je m’ogberin,





Iwofa ko gbodo je mogbede





Omo bibi inun won ni je m’oderin





Bi wo kola biwo kolowo lowo,





Eru ti n se mi ni rami ta mi to mi ni temi o jare





Iwo lomo Olola ti n san keke,





Iwo lomo oloola ti n bu abaja





Agbere ni wa won ki gbowo Ila lowo awa





Eyin lomo ara eru ke omo,





Omo ara eru bere eni





Omo araya le ki omo tode.





Iwo ilu Alfa





Iwo todidere pepepe tenure te k’oroyin


Wednesday, March 6, 2024

Oriki Ikoyi Eso

Oriki Ikoyi Eso

Here is an Oriki for Ikoyi Eso in Yoruba language:




“Ikoyi eso omo owa,



omo aro, omo ase, omo Alaketu.



Omo ilu omi, omo ilu omi tutu.



Adifa fun ewelewele, ti n lo re omo Ikoyi eso.




Won ni ki n ta ori loju ogun,




won ni ki n wa ni ibeji ni.




Ikoyi eso ni won ni ki n pe ni won ni ka toju ona,




bi a ba fi oju ona we won a fi igbala da won.




Awon to gba eyin eranko ni won ni ki n ka ara won mu,




bi a ba fi ara won mu won a fi oju ona we won a fi igbala da won.”

Monday, March 4, 2024

Oriki Ira (Oriki ilu Ira)

Oriki Ira (Oriki ilu Ira)

Oriki Ira




Ira, Laaru Osin, Onira Laage, Iloko Omo Arelu,


Ma relu mi mo, Ori Olori ni k Oya o maa wa kiri Lagbedajo,


Omo Afaja wusi oku ni popo Ira,Omo lele bi otutu


Gingingin loye mu ni le baba won.


Ki iwo yala,kemi yala kere pade L’ajogbori


Ajogborini mi , mi o jo gba eko ototo eyan ni mojo


Gba loro kekere Iloko, oti mu da o die le kekere Iloko,


O ti muda Odi ero Iloko timuda odi iberu eru omo ajoba,


Lo lele agba Iloko nawo nase sile oni ori laabe ni abe se ni Iloko oro


Arelu eyo omo abatabutu oju Okun Olere, Ehin okun ose tu ni kengbe,


Abata butu oju omi kohu koriko .
WHAT IS ORÍKÌ?

WHAT IS ORÍKÌ?

WHAT IS ORÍKÌ?




Oriki is an important and cultural, but unwritten (oral) genre of Yoruba literature that is usually used in praise singing. 




The Yoruba people have very rich cultural oral literature, oriki is one of them.