Showing posts with label oriki. Show all posts
Showing posts with label oriki. Show all posts

Wednesday, March 6, 2024

Oriki Ikoyi Eso

Oriki Ikoyi Eso

Here is an Oriki for Ikoyi Eso in Yoruba language:




“Ikoyi eso omo owa,



omo aro, omo ase, omo Alaketu.



Omo ilu omi, omo ilu omi tutu.



Adifa fun ewelewele, ti n lo re omo Ikoyi eso.




Won ni ki n ta ori loju ogun,




won ni ki n wa ni ibeji ni.




Ikoyi eso ni won ni ki n pe ni won ni ka toju ona,




bi a ba fi oju ona we won a fi igbala da won.




Awon to gba eyin eranko ni won ni ki n ka ara won mu,




bi a ba fi ara won mu won a fi oju ona we won a fi igbala da won.”

Monday, March 4, 2024

Oriki Ira (Oriki ilu Ira)

Oriki Ira (Oriki ilu Ira)

Oriki Ira




Ira, Laaru Osin, Onira Laage, Iloko Omo Arelu,


Ma relu mi mo, Ori Olori ni k Oya o maa wa kiri Lagbedajo,


Omo Afaja wusi oku ni popo Ira,Omo lele bi otutu


Gingingin loye mu ni le baba won.


Ki iwo yala,kemi yala kere pade L’ajogbori


Ajogborini mi , mi o jo gba eko ototo eyan ni mojo


Gba loro kekere Iloko, oti mu da o die le kekere Iloko,


O ti muda Odi ero Iloko timuda odi iberu eru omo ajoba,


Lo lele agba Iloko nawo nase sile oni ori laabe ni abe se ni Iloko oro


Arelu eyo omo abatabutu oju Okun Olere, Ehin okun ose tu ni kengbe,


Abata butu oju omi kohu koriko .
WHAT IS ORÍKÌ?

WHAT IS ORÍKÌ?

WHAT IS ORÍKÌ?




Oriki is an important and cultural, but unwritten (oral) genre of Yoruba literature that is usually used in praise singing. 




The Yoruba people have very rich cultural oral literature, oriki is one of them.

Monday, January 22, 2024

ORIKI ORI

ORIKI ORI

ORIKI ORI






Ori Onise Apere Atete gbeni ju Orisa 

Ori atete niran 

Ori lokun 

Ori nide 

Ko si Orisa ti dani gbe leyin Ori eni 


Ori ni seni ta a fi dade owo 


Ori ni seni ta a fi tepa ileke woja 


Ori ni seni ta a fi lo mosaaji aso oba 

Ori gbe mi 

Ori la mi 

Ori ma pada leyin mi 




Translation 

Ori, the competent Creator Apere


He who is faster in aiding one than the Orisa


He who instantly remembers his devotee


Ori is valuable


Ori is jewelry


No Orisa can favour one without the consent of one’s Ori


It is Ori that aids one for one to be crowned of money


It is Ori that bless one for one to be using beaded walking stick even to the market


It is Ori that bless one for one to be using valuable cloths


Ori, please, support me


Ori, please, bless me

Ori, please, never turn against me.

Saturday, January 6, 2024

Oríkì Onílù

Oríkì Onílù

Oríkì Onílù







Ọmọ afi gúdúgúdú ṣ'ọlá,



Ọmọ afi dùndún ṣ' ọrọ̀,



Ọmọ Àyándìran.



Bí baba mi ti ńlù,


Bẹ́ẹ̀ ni ṣaworo ìlù rẹ̀ ńdún,



Ọmọ alùlù gbowó.




Baba mi ni ń fi dùndún




Sọ̀rọ̀ bí ènìyàn láàrin ìlú,




Ọmọ afi gúdúgúdú fọhùn arò,




L'áàfin Ọba