Showing posts with label proverb. Show all posts
Showing posts with label proverb. Show all posts

Wednesday, August 23, 2023

Tuesday, August 22, 2023

Friday, August 18, 2023

Bí a bá fi àgbò fún eégún, à á jọ̀wọ́ okùn rẹ̀ (Read insight to this proverb)

Bí a bá fi àgbò fún eégún, à á jọ̀wọ́ okùn rẹ̀ (Read insight to this proverb)

Bí a bá fi àgbò fún eégún, 


à á jọ̀wọ́ okùn rẹ̀. 

/


If we hand over a ram to the masquerade, we must release the tethering rope to the masquerade as well. 
[When we make a major move, 


we shouldn't hold back on other relevant, 


even if minor, 

ones; 


finish whatever you start.]

Wednesday, August 16, 2023

Àgbàlagbà tí ò kẹ́hùn sọ̀rọ̀ bá ọmọ wí ní kékeré

Àgbàlagbà tí ò kẹ́hùn sọ̀rọ̀ bá ọmọ wí ní kékeré

Àgbàlagbà tí ò kẹ́hùn sọ̀rọ̀ bá ọmọ wí ní kékeré, 

á kẹtan sáré lórí ọmọ náà tó bá dàgbà, 


tí ẹnu ò káa mọ́. /An elder who won't sharply reprimand a child when young would be compelled to run helter skelter when the child is fully grown, and becomes grossly disobedient.

Sunday, August 13, 2023

A kì í fi oró yán oró

A kì í fi oró yán oró

A kì í fi oró yán oró; 


aforóyánró kì í jẹ́ k'óró ó tán; 


afìkàsànkà kì í jẹ́ ki ìkà ó tán bọ̀rọ̀. /


Do not repay evil with evil; 

those who repay evil with evil 


or wickedness with wickedness exacerbate them.


[Don't seek to get even: 


forgive and just move on; let go and let God]

Friday, August 11, 2023

Thursday, August 10, 2023

ÈÈRÀ KÒ FẸ PÒPÓRÒ DÉNÚ, TRUST YOURSELF

ÈÈRÀ KÒ FẸ PÒPÓRÒ DÉNÚ, TRUST YOURSELF

ÈÈRÀ KÒ FẸ PÒPÓRÒ DÉNÚ
TRUST YOURSELF Ifá ní dùgbẹ̀dùgbẹ̀ òkè níí fò ganranhìn-ganranhìn
Adifafun Èèrà
Èèrà nlọ sínú PÒPÓRÒ lọ ree bímọ sí
Ẹbọ ni Awo pé kí ó
O gbẹbọ níbẹ̀ o rúbọ
Ńse bẹ́erí Èèrà
Bẹẹ rí PÒPÓRÒ
Gúnmọ́-gúnmọ́ niwọn rí
À sé Èèrà kò fẹ PÒPÓRÒ dénú.

Ifá says

Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ òkè is the one that flies here and there
Casted Ifá divination for Èèrà (Ants)
When she was going to to have her babies inside PÒPÓRÒ
The Ifá Priests advised her to perform sacrifices
She performed the sacrifices
If you see the Ants
And PÒPÓRÒ


They are very closed 
Alas! The Ants does not truly love Pòpórò...

Olodumare will make us overcome every tribulations that may come our way.

Sunday, July 16, 2023

Saturday, July 1, 2023

Mo gbọ́n tán, mo mọ̀ ọ́ tán

Mo gbọ́n tán, mo mọ̀ ọ́ tán

Mo gbọ́n tán, mo mọ̀ ọ́ tán, l'agbọ́n ò ṣe l'óró bí oyin. /

Wasps' claim to be the wisest and the best is why they have less potent venom than bees. 


[Humility is it: pride and arrogance weaken; not smart to brag and boast, regardless of your success: no one has it all made]

Friday, June 30, 2023

Nínú ìkòkò dúdú

Nínú ìkòkò dúdú

Nínú ìkòkò dúdú ni ẹ̀kọ funfun ti ńjáde. /


Out of the black pot nonetheless comes the white corn gruel (or pap).
[Write-off no one; no matter how deplorable a situation is, good may still come out of it: always remain positive and keep hope alive.] #