Ìtàn àmọ̀jù níí m'ẹ́yẹ oko ó sùn'gbẹ́
Díá fún Àdàbà súùsúù
Tí ńlọọ́ bú ará Ìṣokùn l'ẹ́rú
Ẹbọ ni wọ́n ní kí wọ́n wá ṣe
Wọ́n kọ'tí ọ̀gbọnyìn s'ẹ́bọ
Ọ̀tún Ìṣokùn ẹrú
Ósí Ìṣokùn ẹrú
Ni wọ́n bá lé Àdàbà súùsúù kúrò ní'lǔu
Ló wá ń sọ wípé
Ọ̀tún Ìṣokùn
Gbogbo wọn ni wọ́n ńse bí Ọba bí Ọba
Ósí Ìṣokùn
Gbogbo wọn ni wọ́n ńse bí Ọba bí Ọba
Ire o!
This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647) For spiritual guidance...We also sell spiritual product for wealth, protection and Open doors.
Post a Comment