no fucking license
Bookmark

ORIKI OGUN (orisa / orisha)

ORIKI OGUN


Ogun lakaiye
Ọsin mole
Ogun alada méjì
Ofi okan sanko
Ofi okan yena
Ọjo ogun nti ori oke bo


Aso ina lo mu bora
Ẹwu eje lowo
Ogun onile owo
Ọlo na ola
Ogun onile Kongun kongun Ọrun
Olomi ni ile feje we
Olaso nile fimo kimo boraOgun apon leyin iju
Egbe lehin omo kan
Ogun meje logun mi
Ogun alara ni n gb’aja
Ogun onire a gb’agbo
Ogun ikole a gb’agbin


Ogun ila a gb’esun isu
Ogun akirin a gb’awo agbo
Ogun elemono eran ahun ni je
Ogun makinde ti dogun leyin odi
Bi o ba gba tapa a gb’aboki
A gba ukuuku a gba kemberiNje nibo lati gbe pade ogun?
A pade ogun nibi ija
A pade re nibi ita
A pade re nibi agbara eje ti nsan
Agbara eje ti ndeni lorun
Bi omi ago
Bomode ba ndale
Ki o mase da Ogun
Oro Ogun leewo
Ara Ogun kan go go go!

This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647) For spiritual guidance...We also sell spiritual product for wealth, protection and Open doors.

Post a Comment

Post a Comment