Ọ̀ṢUN CONSECRATION
ORÍKÌ Ọ̀ṢUN
Ọ̀ṣun is the Yoruba Orisa of love, intimacy, beauty, fertility, and wealth. She is compassionate and sensuous in nature, and she uses her water-element energy for healing and nurturing. She is the Òrìṣà who presides over the divinity of the Ọ̀ṣun river.
Ọ̀ṣun ṣéǹgẹ̀ṣẹ́ olóòyà iyùn!
Arẹwà obìnrin, alágbo l'ódò
A'wẹ'dẹ'wẹ'mò, af'idẹ-rẹ'mọ
Apẹ́níbú-ṣọlá, apẹ́lódò-ṣ'ọrọ̀ ọmọ
Ọ̀ṣun abú'ra Olú
Òwa'yanrìn'wa'yanrìn ko'wósí!
Ọ̀ṣun oníkìí, ẹni idẹ kìí sún
Òyéye-n'ímọ̀, amọ-awo-má-rò
Omi-amọ̀ọ́-rìn, omi a-mọ̀ọ́ sun
Obìnrin gb'ọ̀nà, ọkùnrin ń sá
Ọ̀gbàdàgbàdà l'ọ́yàn
Gbàdàmùgbádámú obìnrin kò ṣe é gbámú!
Oore Yèyé Ọ̀ṣun!
Látójokú, Yèyé ọ̀pọ̀
Ìyá ab'óbìrin gb'àtọ̀, Ládékojú ab'ọ́kùnrin gb'ase
Ìyá tí kò l'éegun tí kò l'ẹ́jẹ̀
Ladekoju ebora tí ń gbé nù omi
Elétíi gb'áròyé, ọ̀gbàgbà tí ń gb'ọmọ rẹ̀ l'ọ́jọ́ ìjà!
Yèyé mi ọl'ọ́wọ́ aró
Yèyé mi ẹlẹ́sẹ̀ osùn
Yèyé mi a'jímọ́-roro
Yèyé mi a'bímọ má yànkú
Yèyé mi aláàgbo àwẹ̀yè
Aríbáni-gbọ́-nípa-t'ọmọ!
Oore Yèyé gbà mí, ẹni a ní ní ń gba ni!
Omi oooo!
Ọta oooo!
Ẹri oooo!
Ẹdan oooo!
Ẹ k'óre Yèyé Ọ̀ṣun oooooo!
Ọ̀ṣun mà ń bọ̀ o - Yàgò lọ́nà o
Oore Yèyé mà ń bọ̀ o - Yàgò lọ́nà o
Grand rising family 👪 🫶🏽📿🙏🏿
This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647) For spiritual guidance...We also sell spiritual product for wealth, protection and Open doors.
Post a Comment