Bi a ba wo oju opolopo awon omo orile-ede Naijiria, a o ri orisirisi ila loju won.
Ogooro eniyan ni ko mo idi re ti a fii ko ila.
Nje kini idi re ti a fi ko ila?
Idahun fun enikeni ti o ba se ibeere yi pin si ona meji. Nigba laelae, ogun ati ote po ni orile –ede Naijiria.
Lakoko yi ni omo nsonu lairo-tele.
Awon alagbara nko awon omo eniti ko ni agbara bi ti won ta. Bi nwon ti n ko omo won be ni nwon nko aya won paapaa.
Beni opo gende (youth) nsonu, ti a nfi won se awaari. Bi a ti nko won la n tawon leru fun awon orile-ede miran.
Bi awon ti a ta leru wonyi, yala lati idile kan naa tabi ilu kan naa ba pade, nwon ko ni mo ara won rara.
Sugbon awon agbalagba ronu pe o ye ki kini kan bi ami wa, eyi ti nwon yoo fi maa mo ara won.
Ti nwon o si le so lesekannaa ilu ti eniyan kan ti wa ni kete ti aba rii.
Ogbon ila kiko yi kii se ti gbogbo orile-ede yi ni lati ibere bikose ohun ti awon eniyan orile-ede yi jogun lati Iwo-Orun nibi ti asa naa ti koko bere.
Alaye keji fun ila kiko ni pe boya awon eniyan Iwo-orun nibi ti asa yi ti bere ro pe yoo bukun ewa ara won nipa sise bee.
Bi a ba wo ju elomira ninu awon Okunrin tabi awon obinrin ti o ko ila, ao rii pe ila naa dara pupo loju opolopo won.
Dajudaju, asa lati bu si ewa ara ni iru awon bee ka ila kiko si. “Bi a ko ba tori isu jepo, a o tori epo je isu”.
Bi a ba wo finnifinni, a o rii pe ila yi yato si ara won lati agbegbe si agbegbe tabi ilu si ilu nibomiran.
Awon Oyo nii ko orisirisi Abaja, Pele ati Ture. Nwon tun nko Abaja meta-meta, tabi Gombo, Keke ati Gombo papo.
Awon Ekiti a bu meta-meta ti o gbooro, tabi eyo kan soso ti o gbooro, tabi meta oro lori meta ibu ti o gbooro.
Awon Egba ni nko meta-meta ti ko gun ti ko si gbooro. Awon Ijebu a maa ko meta-meta tabi meta loke, meta ni isale re.
Awon Owu naa mbu Abaja, nwon si mbu Keke pelu. Pupo ninu awon Ife kii kola, sugbon awon miran nko meta-meta nigba miran.
Awon Ijesa nko mefa. Ondo nko meta-meta. Awon Iyagba nko meta-meta ti o fere papo l’eba enu won.
Ogunlog ile la ti pa asa yi re, sugbon opolopo idile wa ti ko fe fi asa yi sile rara. Lara awon apeere iru awon ila ti awon Yoruba ma n ko niwonyi lati fi dawaloju pe awon ila wonyi yato si ara won lati ilu ati ile si ara won.
Source of Article: https://www.orisa.com.ng
AJE NLA the son of OBATALA is registered with CAC No: 8022733
This Article was written by AJE NLA the son of OBATALA with +2347031178647.
You can contact AJE NLA for ...
ODU OBATALA Consultation
Egbe Orun INITIATION
OSUN Initiation
Begging of the elders
Feeding of ORISA OSUN, OBATALA, Egbe Orun, TAJENIKARO (AJE that fights for your wealth), AJELETI (AJE from IYAAMI), ONIMERE (for all Emere), AJASORO (Revenge and door opener), AJE OLOKUN, ESU, ELEGBA (Justice and way opener) etc.