Be e ko, iyato wa ninu won. Ka muni ni Iwofa san ju ka muni ni leru lo.
Nigba t eru ba n sise ninu ojo ati oorun, ti oju re npon bi aso oyin ati ara re si ri siosio bi ti elede, sebi I se ni Iwofa I se tire ni iwon, ti alo ile olowo re jeje.
Gege bi a ti mon wipe ohun ti a fi se eru a ko le fi se Iwofa nitoriwipe arapa la nra eru eni, bi o ku, bi o ye, ko da nkan kan amuni ko si a fi awoni roro lasan.
Ilo ti an lo Iwofa yato patapata si ti eru nitori pe ona ti a gba ri won yato gidigidi. Eru ni eni ti a mu wa ile lati oju ogun.
Bi o se omode, bi o se agbalagba bi a ba ti muu de odede, abuse ti buse.
O di ko maa sise fun eni bi akura, ki a ran an ni igba ise ki o je leralera. Bi o ba si ku, bi igba ti ewure eni ba ku ni.
Sugbon ti Iwofa yato lopolopo. Iwofa ni eni ti a fi ya owo, ti mba ni sise titi onigbese yoo fi ri owo re san.
Gegebi a ti mo pe ika owo ko dogb, ti ese paapaa ko fi ori-kori.
Bi a ti ri oloko nla ninu awon baba nla wa, bee ni a si ri supe eniyan ti ko le so kobo meta di kobo marun ninu won.
Awon oloko nla ni awon alagbara, ti nwon n sise ti won si n lowo lowo. Ko si iru bira ti nwon ko le da, nitori bi nwon se n kole mo ile ni nwon si leesin leekan.
Iru awon eniyan wonyi bi a lu won gba, a o ba owo lowo won, bi a ba ji won loju orun pelu kobo-kobo ni.
Awon ti ko ni iru ebun bee a lo ya owo fun gbogbo ohun pataki ti nwon ni lati se. Se eni ti ko ba le je “Saka” se a je “Soko”.
Bi a ba to ile ko a o ko ile, bi a ba to aya fe, a o fee. Bi a ba si to awon nkan wonyii se ti ko si kobo nko?
Dandan ni ka gbe itiju ta ka lo si ile eni ti o ju ni lo. Ko si ohun meji bikose lati ya owo.
Bi alagbara ba si ronu re titi a ya oluware lowo. Eni ti o lo ya owo ni yoo se ileri ohun ti o maa se. Bi o ba je eniti ko ti bi omo rara, o le fi ara e s’ofa owo ti o ya. Bi o ba si je eni ti o ti bi omo, yoo fi omo re s’ofa owo ti o ya.
Iru omo bee ti a fi s’ofa owo ti a ya ni a n pe ni Iwofa. Ise Iwofa yi ni lati ba olowo baba re se ise ni ile ati l’oko. Ohunkohun ti a ba ni ko se lo gbodo se.
Sugbon ohun ti a ko ba le fun omo ara eni se a ko gbodo fun Iwofa se.
Nitori bi ope bi o ya, Iwofa yo pada lo si ile re. “Iwofa n bo wa di oga, akoko ti yoo se ni eda ko mo”. Bi a ba daso fun omo ara eni a o da fun Iwofa pelu.
Onje ti omo wa ba je naa ni Iwofa yoo je. Eni ba gba Iwofa sodo gbodo sora re gidigidi ki o rii pe oun ko si iwofa naa lo. Iwofa ko gbodo ku si ile eni, ki gbese ma baa ju eyi ti o wa nibe fun olowo.
Iwofa yi yoo maa sise titi baba re yoo fi san gbese re tan fun olowo. Ni aye igaani awon obi n fi omo won sofa tori kobo marun ti an pe ni egbaa tabi kobo mewa ti a n pe ni egbaaji.
Elomiran le se iwofa fun osu meta tabi mefa ki owo naa to pe. Bi o ba si je owo to to egbaarun ti a npe ni kobo medogbon tabi oke kan ti a npe ni aadota kobo, dajudaju iwofa yoo se to ise odun meji si meta.
Baba ti o fi omo re sofa ko ni joko lasan, oun naa yoo maa sise taratara ko ba le tete mu omo re pada. O le san owo naa leekan tabieemeji. Sugbon ojo ti o ba san owo re tan ni omo re yoo kuro ni oko ofa.
A ri iwofa miran ti o je pe bi o ba pe pupo a fe di ara ile eni. Nitori pe awon miran wa ti awon obi won ku ki nwon to san gbese won. Iru iwofa be yoo ma sise lo. Yoo lo opolopo odun, yoo si maa se bi omo ni ile olowo re. Iru awon bee le fe iyawo nile olowo won, ki nwon si di eni a nfi gbese naa ji patapata.
Mo fe je ki a mo pe okunrin nikan ko la fi ma n s’ofa. A le fi okunrin s’ofa sodo okunrin ati obinrin sodo obinrin. Bi a ti nya owo lodo okunrin l’n nya owo lodo obinrin.
Iwofa okunrin a ma ba olowo re se ise oko, Iwofa obinrin a maa ba olowo re se isekise ti o ba kan nile olowo re.
Nwon le ran owu ki nwon si hun aso. Ojo mefa-mefa ni iwofa I se ise l’oko olowo re ninu ose pelu ero pe yoo lo ojo kan ti o ku fun ara re.
Ninu sise eyi ni oro naa ti suyo eyi ti a npe ni IWOFA tabi IWO-EFA (sise ise ojo mefa-mefa).