Friday, May 19, 2023

Oriki Nile Yoruba

SHARE
Àsà kan pàtàkì tí àwa Omo Yorùba ń gbé sonù báyìí ni àsà oríkì kíkì. 
Ní ilè Yorùbá kò sí nnkan náà tí kò ní oríkì yálà eranko , igi, ouñje , ìlú, èèyàn, bòròkìní, ìdílé tàbí orílẹ̀. Orísirísi ìdílé ni ó sì ní oríkì ti won.Kíni oríkì gan? Oríkì jé àwon òrò ìsírí tí àwon yorùbá máa  ń Fi ki ara won. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwúlò ni ó rọ̀mọ́ kíki Oríkì. Àwon olórin a máa lò oríkì láti lè jé kí àwon ènìyàn ojú agbo ba à lè náwó fún won. Àwon òbí náà a máa lò oríkì lati kí Omo won láàárọ̀, láti jékí ó se ise tí wón bá rán- an tàbí láti fi ìdùnnú won hàn sí omo tí ó bá se ohun tí wón fẹ́. Àwọn ọdẹ náà sábà máa ń ki oríkì àwọn ẹranko nígbà tí wọn sun Ìjálá (eré).
Orísirísi ònà ni a fi ñ ki ènìyàn. Bí a ti ń ki oba béè kọ́ ni à n ki ènìyàn lásán. Oríkì Bọ̀rọ̀kìní yàtọ̀ sí ti ìjòyè  À máa ń ki ọba bí agbára rè bá se tó, A lè lè kìí sí ọwọ́ tí ó bá yọ nígbà tí ó gun orí oyè tàbí ìté, a sì tún lè kìí láti rán-an létí àwon àseyórí àwon baba ńlá rẹ̀. 

Bí Omo bá jí lówùúrò kùtù bí ó bá lọ kí bàbá àti ìyá rẹ̀, oríkì ni wón á lò láti ki Omo náà. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bí Omo eni bá dára káwí, kìí se pé a fé Fi saya. Oríkì tí a ki Omo eni lówùúrò kùtù tàbí lákòókò tí ó wu ni fihàn pé ìwà tàbí ìse Omo béè wu ni. A kìí porúko eni ká báni wi, a kìí porúko odò kódò gbé nilo béè náà ni a kìí poríkì Omo kí inú rẹ̀ má yọ́ síni. Bákan náà ẹ̀wẹ̀, a lè ki ènìyàn sí orúkọ rẹ̀, pàápàá jùlọ àwọn orúkọ àmútọ̀runwá bíi Ìdòwú, Ìgè, Òjó, Dàda, Àjàyí abbl.
Orísirísi òrò ìjìnlè, àfiwé, àpónlé abbl ni Ó sábà máa ń súyo nínú oríkì.Fún àpeere:OBA : “kábíyèsí oba ‘lúwayé,
Odundun aso’de dero
Oba adé-kí-ilé-rójú
Oba adé-kí-ònà-rorún
Arówólò bí òyìnbó
Ó Fi lé Wu ni
Ó fònà Wu ni
Ògìdìgbà tí ń gbà ara
àdúgbò
Oba atáyéro bí agogo
A lè ki ènìyàn sí ìdílé rè, ibi tí a ti bíi, yálà jagunjagun ni tàbí olórìsà kan ni. Sùgbón oríkì tí ó je mó ìlú ènìyàn tí a sì le lò fún enikéni ní ìlú náà ni a ń pè ní orílẹ̀, ó jẹ́ ìsọ̀rí oríkì. Kòsí pàtó ìgbà tàbí àkókò tí a kò le ki ènìyàn.
Ohun mìíràn tí a tún se àkíyèsí nípa oríkì ni pé  bí a tí n ki okùnrin béè náà là ń ki obìnrin pèlú. Kòsí eni tí kò ní oríkì tirè nínú won. 
Àwon oríkì tí ó je mó obìnrin lè súyo nípa orúko won tàbí ilé tí a ti bí won. Bí ó bá sì jé èyí tí ó je mó ìdílé ni, okùnrin àti obìnrin ni a kì oríkì béè fún. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, fún ìdílé tí a ti ń gbé égúngún a lè kì wón sí oríkì Ọlọ́gbìín tàbí Aláràn-án.
Oríkì fún àwon ìbejì náà kò gbẹ́yìn nínú oríkì kíkì, nítorí won jẹ́ nǹkan pàtàkì tí àwọn Yorùbá máa ń kàsí. Oríkì yìí wópò lẹ́nu àwọn àgbàlagbà àti àwọn abiyamọ. Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn àbáláyé àwọn Yorùbá kíki Oríkì àwon Orìsà náà ń kó ipa pàtàkì .

Láì sí àníàní Oríkì jẹ́ nǹkan pàtàkì tí kò ṣe fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní àwujọ àwon Yorùbá. Àwọn Akéwì tàbí apohùn Yorùbá gbádùn láti máa Fi oríkì dá ènìyàn lárayá yálà níbi ìgbéyàwó, ìwúyè, ìkómo, ilé sísí ni tàbí ohun àyò mìíràn tí a máa ń se.

Sí ẹ̀yin olólùfẹ́ wa, ǹjẹ́ ẹ̀yin mo Oríkì orílẹ̀ tàbí ìdílé yín? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ ẹ tẹ̀ẹ́ gẹ́ bí àríwísí sí àpilẹ̀kọ yìí.Àjose wa kò ní bàjẹ́ láṣẹ Èdùmàrè.

This Article is written by AJE NLA (whatsapp +2347031178647).For the following:::

IFA consultation and Divination

Egbe Orun initiation

Appeasement of Egbe Orun

Yes and No questions

Feeding of Ori (inner head)

Feeding of ORISA

IFA INITIATION

Solutions to Problems

Source: https://www.orisa.com.ng

SHARE

Author: verified_user

AJE NLA Spiritual Traveller | OLOBATALA | OMO OLOKUN, OMO ORISA | BABALAWO OMO ORUNMILA | CEO www.orisa.com.ng | +2347031178647 For IFA Consultation, Divination, Yes / No questions , spiritual guidance, Dream interpretation etc whatsapp https://wa.me/2347031178647

0 $type={blogger}: