🖊️Mura si ise ore mi* *
🖊️Ise ni afi ndeni giga* *
🖊️Bi ako ba reni fehinti* *
🖊️Bi ole la a ri* *
🖊️Bi a ko ba reni gbekele* *
🖊️A tera mo ise eni* *
🖊️Iya re le lowo lowo* *
🖊️Baba re si le leshin le kan* *
🖊️Bi o ba gboju le won* *
🖊️Ohun te tan ni mo so fun o* *
🖊️Ohun ti a ko ba jiya fun* *
🖊️Se kii le tojo rara* *
🖊️Ohun ti a ba fara sise fun* *
🖊️Ni npe lowo eni* *
🖊️Apa lara* *
🖊️Igunpa ni iye kan* *
🖊️Bi aiye ba nfe o loni* *
🖊️Ti o balowo lowo* *
🖊️Aye a ma fe o lola* *
🖊️Jeki o wa ni ipo atata* *
🖊️Aiye a ma ye o si terin-terin* *
🖊️Jeki o deni ti rago* *
🖊️Ko o ri bi aiye ti nyinmu si o* *
🖊️Eko si le seni doga* *
🖊️Mura ki o ko dara-dara* *
🖊️Bi o ri opo eniyan* *
🖊️Ti n fi eko serin rin* *
🖊️Dakun ma fara we won* *
🖊️Iya nbo fomo ti ko gbon* *
🖊️Ekun mbe fomo ti o nsa kiri* *
🖊️Ma fowuro sere ore mi* *
🖊️Mura si ise ojo nlo.*👌🏼👍🏼
Post a Comment