Oriki Oyá
Oya òòsà tí í roko ré léyin.
Oya ní í tárúgbó se lóge.
Obìrin gbandikan,
Eégún a san dórí.
Oya ni mó máa bo.
Pará Ogun bí e n palé.
Irú Oya ò sí lórun,
Iyàwó orí ògún.
Oya kan, Sàngó kan.
A tó ó kàn bí òkè.
A málejò yíká ile.
Baálé dí méji, ara ò rò kan.
Onínúolá, oko o!
Oya a rìn léji.
Olùwaà mi èjè níyi Ogun.
Oya òrírì!
A-wo ni fírí, bí enì tí ò rí ni.
A-sòwò kéékéèké gbowó è ní kisi.
Oya a rinà bora bí aso.
Ina ma ní égún o,
Ina tí njo ní laí towo bo’ ná.
Oya òwàrà, bíi’ ná jóko láàró.
A fijà dófirì, niwáju jagunjagun.
Oya alágbára inu aféfé.
Oloju ojo, a ri won dé òguluntù.
Oya bí àkúfó ikókò tí nró kókó-kókó.
Oya lé babaláwo kò dúrò kó’ fá.
Oya rorò!
A rìn dengbere nínú aféfé.
Oya, a tún orí eni tí kò sunwon se.
A so ibànújé dire.
Alágbára obìrin òòsà.
Màá bá o sepò.
Odó awuwo lóhùn, bí ààrá.
Oya órirí a wúwo má se wa.
Oya má se ba tèmi je,
Oya, òrìsà to n gbà ní lówó isé.
Oya oláà re lèmí n je ò,
Olá tí kékeré awó je tó fi mó gbódú.
Awa kò lóhun méji bí
Discover more from ORISA BLOG
Subscribe to get the latest posts sent to your email.